PDP LO NI KOGI, A SI TI ṢETAN LATI GBAJỌBA - WADA LERI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSunday, September 8, 2019

PDP LO NI KOGI, A SI TI ṢETAN LATI GBAJỌBA - WADA LERI

Oludije sipo gomina ipinlẹ Kogi ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan labele, Ọgbẹni Musa Wada ti sọ pe asiko naa ti to fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP lati gba ijọba ipinlẹ Kogi kuro lọwọ awọn amunilẹrulo n ṣakoso lọwọ.

Wada lo sọrọ naa lonii niluu Abuja lasiko to n bawọn oniroyin sọrọ fun ti ipalẹmọ idibo gomina to n bọ lọjọ kẹrindinlogun oṣu kọkanla ọdun yi, to si ni gbogbo awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu PDP lo ti ṣetan lati jumọ gba ijọba naa.

O lawọn ọmọ ipinlẹ Kogi ko bẹru gomina to wa lori ipo lasiko yi lati le e danu bi asiko ba to, nitori pe ẹgbẹ oṣelu PDP lo ni ipinlẹ Kogi.

Bẹẹ lo sọ pe igbaradi lati bẹrẹ ipolongo ati ikede idibo ti bẹrẹ, tawọn yoo si ṣe nilana alaafia ati iṣọkan kaakiri gbogbo ipinlẹ naa, ati pe awọn ko nii gba iwa ipanle tabi jagidijagan laaye.

O wa a gbawọn ọmọ ipinlẹ naa lamọnran pe ki wọn ma ṣe gba lati jẹ ki ẹgbẹ oṣelu APC ri wọn lo lati huwa ipanle tabi jagidijagan lasiko idibo, bi ko ṣe pe ki wọn gba alaafia laaye lati jẹ ki otitọ jọba.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI