O MA ṢE O, EYI NI ABAYỌMI ADIGUN, OṢIṢẸ TẸLIFIṢAN AIT ṢE KU SỌWỌ AWỌN AJINIGBE L'ABUJA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 4, 2019

O MA ṢE O, EYI NI ABAYỌMI ADIGUN, OṢIṢẸ TẸLIFIṢAN AIT ṢE KU SỌWỌ AWỌN AJINIGBE L'ABUJA

Iroyin ti ko dun mọ ẹnikẹni ninu bawọn ajinigbe ṣe ji ọkan lara awọn oṣiṣẹ tẹlifiṣan African Independent Tlelevision, AIT, iyẹn Abayọmi Adigun, ti wọn si pa a danu.

Ẹka ileeṣẹ naa to wa niluu Ilọrin la gbọ pe wọn ti gbe Abayọmi kuro laipẹ yi, lati lọọ darpọ mọ awọn ikọ to n ṣeto Kakaaki niluu Abuja.

Alẹ ọjọ Sande to kọja yi la gbọ pe Abayọmi gbera nile ẹ lati lọ sibiṣẹ, to si wọ ọkọ lagbegbe Kubwa-Aya, nibi to ti ko sọwọ awọn ajinigbe ti wọn pe ni "One Chance" naa.

Nigba ti wọn ko tete ri Abayọmi lati wọ iṣẹ lalẹ ọjọ naa la gbọ pe wọn bẹrẹ sii pe aago ẹ, ṣugbọn ti ẹnikẹni ko gbe e.

Iyalẹnu lo si jẹ pe nigba ti wọn maa pada ri Abayọmi, oku ẹ ni wọn ba lẹgbẹẹ titi, iyẹn lopopona Kubwa, ti wọn ti gun un wẹlẹwẹlẹ.

A gbọ pe iwadii awọn ọlọpaa to bẹrẹ lori awọn to ṣeku pa ọkunrin naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI