XENOPHOBIC ATTACK: AWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRIA TÍ YARÍ PÉ ÀWỌN NÁÀ YÓÒ GBẸ̀SAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 4, 2019

XENOPHOBIC ATTACK: AWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRIA TÍ YARÍ PÉ ÀWỌN NÁÀ YÓÒ GBẸ̀SAN

Àwọn ọmọ Nàìjíría ní ìpínlẹ̀ Eko ti gba ìgbòrò láti kọju ìkora ẹya miràn ti àwọn South Africa ń ṣe fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Ilé ìtàjà ìgbàlóde Shoprite tí agbègbè Lekki ní ọmọbinrin kan ti gbe ìwé iléwọ láti bu ẹnu àtẹ́ lu ìwá akọlu ti àwọn South Africa n ṣe si awọn ọmọ Nàìjíríà.

Àwọn míràn tíll ń kigbe pé ki wọ́n dáná sun ilé itaja náà lójùnà àti ranṣẹ́ pada sí àwọn ènìyàn South Africa gẹ́gẹ́ bi ẹsàn.

Tí ẹ o bá gbàgbé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè South Africa tí ń ko sọọbu ti wọ́n sì ń pa àwọn ọmọ Nàìjíríà ni orilẹ̀-èdè wọ́n.

Ìròyìn sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gba ìgbòro ló ti pàdánù àwọn ẹbí wọ́n nínú wàhàlá tí àwọn ará South Africa ń dásílẹ̀.

Ẹ fi ọlọ́pàá wa sáàrin ọlọ́pàá yín ní South Africa fún ààbò àjèjì - ìjọba Nàíjíríà bèèrè

Ijọba ilẹ Naijiria ti kesi ijọba ilẹ South Africa pe ko yara tete setan lati san owo gba ma binu fun awọn ọmọ Naijiria to fara kaasa ọpọ ikọlu lati ọwọ awọn ọmọ orilẹede rẹ.

Minisita fọrọ ilẹ okeere lorilẹede Naijiria, Gofferey Onyeama lo tẹ pẹpẹ ibeere naa siwaju asoju ijọba ilẹ South Africa to ransẹ pe laarọ oni.

Bakan naa lo koro oju si ijọba ilẹ South Africa pe o mọọmọ n fi ọrọ titi ọwọ bọ iwe adehun igbọraẹniye laarin orilẹede mejeeji falẹ.

Iwe igbọraẹniye ọhun lo wa lati wa ojutu si bi awọn ọmọ ilẹ South Africa se maa n kọlu awọn ajeji to wa lorilẹede wọn.

Bakan naa tun ni ijọba Naijiria n beere lọwọ ilẹ South Africa pe ko fi awọn ọlọpa Naijiria sinu awọn ọlọpa ilẹ South Africa, ki wọn si tun wa lara awọn asoju ilẹ wa ni South Africa.

"Bí ẹ̀bẹ̀ kò bá dẹ́kun ìkọlù South Africa, ẹ gbé iléeṣẹ́ aṣojú rẹ̀ ní Nàíjíríà tìpa"

Ẹnu lasan ko le dẹkun ọrọ bi awọn ọmọ bibi orilẹede South Afrika se n kọlu awọn ajeji, taa mọ si Xenophobia, eyi to ti wa n di lemọ-lemọ bayii, ayafi ki ijọba Naijiria gbe igbeṣẹ to lagbara lori rẹ.

Eyi ni ero aṣoju ilẹ Naijiria sorileede Uganda tẹlẹ ri, Ambassador Omolade Oluwateru, ẹni to tun ti jẹ igbakeji gomina tẹlẹ nipinlẹ Ondo.

Ẹ́ gbọ Oluwatẹru siwaju si: 

Ambassador Oluwateru daba yi gẹgẹ bii lọna abayọ nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, nipa ariwo to gbode lori bi awọn ọmọ orileede South Africa ṣe n dẹyẹ si awọn ọmọ Naijiria.

Oluwateru ni o ṣeni laanu pe orileede South Afrka ti Naijiria ti ṣe loore to pọ, ni yoo ma wa fi ẹ̀yin ọbẹ jẹ Naijiria niṣu.

Awọn ọmọ South Afrika n kọlu ibudo itaja ọmọ Naijiria 
O ni bi ọwọja idẹyẹsi yii ti ṣe wa peleke bayi, ijọba Naijiria gbọdọ gbe igbese to le, ki South Afrika ba le mọ pe ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ẹmi awọn ọmọ ilẹ rẹ lẹyin odi.

''Lẹyin ti Naijiria ba parọwa si South Afrika ti wọ́n ko gbọ, ohun to yẹ ni ki wọn paṣẹ ki aṣoju Naijiria ni South Afrika pada wa sile ni kiakia''

O tun ṣalaye pe ti igbeṣẹ yii ba kọ ti ko dẹkun ọrọ naa, ki Naijiria ti ileeṣẹ asoju South Afrika to wa ni Naijiria pa, ki wọn si da aṣoju wọn pada si ilẹ wọn.

Nigba ti a beere boya Naijiria le gbe awọn ọmọ ilẹ rẹ to wa ni South Afrika pada wa sile, Otunba Oluwateru ni o ṣeeṣe ṣugbọn kii ṣe gbogbo eeyan naa ni yoo fẹ pada wa sile.

''Awọn miran le e ni iṣẹ ti wọn n ṣe nibẹ ati pe, ti a ba gbe wọn pada, ki ni wọn fẹ́ maa wa ṣe nile? Ẹkọ gbigbona lọrọ yi, o gba ki a fi suuru to''

Kini Ijọba Naijiria ti ṣe?

Lọwọlọwọ bayii, ijọ̀ba orilẹede Naijiria ti ransẹ ke si asoju ijọba ilẹ SZouth Africa to wa ni naijiria si ibi ipade kan.

Bakan naa, Minisita fọrọ ilẹ Okeere, Geoffrey Onyeama loju opo Twitter rẹ, ti wa bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ yii, to si ni Naijiria yoo gbe igbesẹ to peye lori ọrọ naa.

O ni o to gẹ bi wọn ti ṣe n dana sun awọ́n ile itaja ọmọ Naijiria lorileede South Afrika.

Sugbọn ọpọ Naijiria lo n woye pe ijọba orilẹede yii ko tii se ohun to yẹ, to ba si fẹ dẹkun ikọlu yii, o gbọdọ san sokoto rẹ ko le ni.

"A kò ní ra ọjà South Africa mọ́, a ó gbẹ̀san oró tí wọn ń dá wa - Ọmọ Nàíjíríà fárígá"

Igi gogoro ma gun mi loju, ati okeere la tii wo o, o wa to asiko bayi ki ijọba Naijiria wa wọrọkọ fi ṣada lori ọrọ ikọlu South Afrika sawọn ọmọ Naijiria to n di lemọlemọ bayii.

Eyi ni ero ọkan ọpọ ọmọ Naijiria loju opo Twitter lori iwa idojule ti awọn ọmọ South Afrika n hu si awọn ọmọ Naijiria nilẹ wọn.

Kaakiri oju iwe iroyin ati loju ayelujara ni iroyin ati fọnran fidio orisirisi ti n ṣe afihan bi wọn ti ṣe n doju ija kọ awọn ọmọ Naijiria ati ọmọ ilẹ Afrika miran.

Idunkoko awọn ọmọ South Afrika mọ awọn ọmọ orileede Afrika miran lẹnu ọjọ mẹta yii jẹ ohun to n fọwọ kan ọpọ eeyan lẹmi.

Lara awọn to ti ke gbajare yii la ti ri gbajugbaja sọrọ sọrọ nii, Daddy Freeze, ti o ni oun ko ni ra ọja kankan to ba jẹ ti orileede South Afrika mọ.

Arabinrin Faithe marere da lohun pada ti o si darukọ awọn ile itaja ti o jẹ ti South Afrika, to yẹ ki awọn ọmọ Naijiria dẹyẹ si.

Idẹyẹsi awọn ọmọ ilẹ Afrika lati ọwọ awọn ọmọ South Afrika ko ṣẹṣẹ ma waye.

Lọpọ igba ni awọn ọmọ Naijiria ti ma n farakasa iṣẹlẹ yii ,ti o si ti ma n mu ki awọn eeyan kesi ijọba awọn orilẹede mejeeji lati mu opin ba iru iwa yii.

Pupọ awọn ileeṣẹ South Afrika lo ti pẹka de Naijiria ti wọn si n ri ere tabua lọdọ awọn eeyan Naijiria.

Eyi wa lara ohun ti o mu ki awọn eeyan Naijiria ma faraya, bi awọn ọmọ South Afrika ko ti ṣe ni ẹmi amumọra fun awọn eeyan miran.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI