ỌMỌ ALE YORUBA LO MAA SỌ PE FANAKULA NI EDE YORUBA JẸ - ỌMỌWE FAJẸNYỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 3, 2019

ỌMỌ ALE YORUBA LO MAA SỌ PE FANAKULA NI EDE YORUBA JẸ - ỌMỌWE FAJẸNYỌ


Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
Aarẹ ẹgbẹ awọn olukọ ede Yoruba nile ẹkọ awọn olukọni tijọba apapọ ni gbogbo orilẹ-ede Naijiria, Ọmọwe Sọji Aderẹmi fajẹnyọ ti sọ ọ nita gbangba pe ọmọ ale Yoruba lo maa sọ pe ede Yoruba ki i ṣe ojulowo ede, wi pe fanakula ni, nitori pe gbogbo akọtọ ede lo wa nibẹ patapata.

Ọmọwe Fajẹnyọ lo sọrọ naa lai pẹ yi nigba to n b'AWIKONKO sọrọ lori ipo ti ede Yoruba wa niluu Abẹokuta. Nibẹ lo ti sọ pe ede tawọn Oyinbo wa n fi owo kọ ni ede Yoruba jẹ, tori pe o gbajumọ daadaa.

Fajẹnyọ to tun jẹ Olukọ Agba Ede Yoruba nile Ẹkọ awọn Olukọni Agba ti Ijọba Apapọ (Chief Lecturer, Federal College of Education), eyi to fikalẹ si Oṣiẹlẹ niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun tun fi kun ọrọ rẹ pe bi awọn ọmọ Yoruba ba pa ede ti patapata, adanu nla ni yoo jẹ, nitori pe lawọn ile ẹkọ fasiti kọọkan lorilẹ-ede Naijiria lo jẹ pe awọn Oyinbo lo n kọ ẹkọ ede Yoruba julọ, eyi to sọ pe ko bojumu to.

Ninu ọrọ rẹ, Ọmọwe Fajẹnyọ sọ pe “Ina ede ti n ku nilẹ Naijiria lojumọ to mọ lonii, oriṣiriṣi nnkan lo si n fa. Akọkọ, o bẹrẹ lati ọdọ awọn obi ati alagbatọ ninu ile. Ọpọ awọn obi ni wọn ko sọ ede Yoruba sawọn ọmọ wọn mọ, ede Gẹẹsi ni wọn fi n ba awọn ọmọ wọn sọrọ. Yatọ si eyi, ọpọ awọn obi ni wọn ko sọ awọn ọmọ wọn ni orukọ Yoruba mọ, nigba to jẹ wi pe awọn obi gan an ti n yi orukọ wọn pada si nnkan min in.


“Ẹlẹẹkeji ni awọn ile ẹkọ, paapaa awọn aladani ko faaye gba ki wọn maa kọ ede Yoruba, wọn a wa maa sọ pe kawọn ọmọ wa ye e sọ fanakula ‘don’t speak vernacular’, to si jẹ pe awọn gan an ni ko mọ itunmọ fanakula. Tori pe fanakula ni ede ara-oko, iyẹn awọn ede ti ko ni akọsilẹ tabi akọtọ, to si jẹ pe ede Yoruba ni.



“Ninu idanilẹkọọ ti Oloogbe Ọjọgbọn Fafunwa ṣe lọdun 2008, o ni ede Yoruba lo wa ni ipo kẹfa ninu gbogbo ede ti a n sọ lagbaye, awọn to ṣaaju rẹ ni ede Gẹẹsi (English), Faranse (French), Potogi (Portuguese), Larubawa (Greek) to si jẹ oke-okun lọhun lawọn ede naa ti wọpọ si julọ, ṣugbọn ti a ba wo ede Yoruba, a maa ṣakiyesi pe ṣe lo tan kalẹ, to si jẹ pe ile ni adiẹ ko ti niyi.



“Lawọn ile ẹkọ girama gan, ijọba ti pọn ọn ni dandan pe ki wọn maa kọ ẹkọ naa, to si jẹ pe ijọba gan an tun jẹ okunfa nitori pe wọn ko gbarauku ti i. Bẹẹ ni ajọ to n mojuto idagbasoke ẹkọ ati iṣẹ iwadii lorilẹede Naijiria, eyi ti wọn n pe ni National Education and Development Council lo gbe ofin yi kalẹ, to sọ pe wọfun lo gbọdọ jẹ, o si tun wa tako agbekalẹ ati ilana eto ẹkọ wa, nitori pe ilana eto ẹkọ wa ti a pe ni National Policy on Education ti wọn ṣe atunṣe ẹ lọdun 2005 ṣi wa nibẹ pe dandan ni ẹkọ ede abinibi mẹta, iyẹn ede Yoruba, Igbo ati Hausa.



“Yatọ si eyi gan, awọn bọrọkini lawujọ wa, wọn kii sọ ede Yoruba. Bẹẹ lawọn oloṣelu ma n gbiyanju lati sọ Yoruba tipatipa, ṣugbọn ti wọn ba wọle tan, ede Gẹẹsi ni wọn maa mu sẹnu. Awọn Ọba alade wa naa tun pẹluu, nigba ti wọn ba n ṣeto ọba jijẹ lọwọ, ti wọn wa nipebi, bo tilẹ jẹ pe wọn ko tẹle ilana eto lati jẹ Ọba mọ lasiko yi, wọn ki i yẹ Ifa wo bii ti atijọ mọ.



“Bi wọn ba fi wọ aafin bayii, ede Yoruba ti sọnu, ko da a, bawọn alejo ba wa a ki wọn lati ilu miiran ti wọn ko gbọ ede Yoruba, ede Gẹẹsi ni wọn a fi ba ara wọn sọrọ, to si jẹ pe awọn Hausa ki i ṣe bẹẹ. Hausa maa lọ wa ogbufọ ti yoo maa tu ọrọ wọn si ọna ti yoo ye awọn alejo kaka ki wọn sọ Gẹẹsi. Nnkan to yẹ ki awọn Ọba alade wa naa ma a ṣe ni yii, awọn Ọba to yẹ ki wọn maa gbe aṣa ati ẹsin wa larugẹ ko ṣe e mọ. Awọn Ọba ati ijọba wa wa lara bi ina ede Yoruba ṣe n jo ajorẹyin. Bẹẹ lawọn olukọ ede Yoruba miran si wa to jẹ pe wọn n farapamọ, wọn ki i fẹ kawọn eeyan mọ pe olukọ ede Yoruba lawọn.



“Ṣugbọn ni temi, beeyan ba sọ ede Gẹẹsi si mi, Yoruba ni maa fi da a lohun. Mo si fẹ ko di mimọ fun un yin pe bi wọn ba ni ki n sọ ede Gẹẹsi, maa sọ lailabawọn nitori pe ẹni to ba ti ni imọ nipa ede yoo ni imọ nipa awọn ede yooku, paapaa ede Gẹẹni nitori pe inu agbada ajọ ti wọn n pe ni Phonetic Association ni gbogbo ti mu ìró ohun ti a n lo. Awa ti a si ni imọ nipa ede la ma n ri awọn aṣiṣẹ asawọ ede iyẹn interference to ba n jẹyọ.”


Bakan naa lo wa a gba ijọba lamọnran pe bi wọn ba ti n gbe ofin kalẹ, ki wọn ri i daju pe wọn n yan igbimọ ti yoo maa tọpinpin bi ofin naa ṣe n fẹsẹ mulẹ, nitori pe aitọpinpin lo n fa a ki ofin ma fẹsẹ mulẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI