SANWO-OLU BANUJẸ NITORI IKU TINUBU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉThursday, September 5, 2019

SANWO-OLU BANUJẸ NITORI IKU TINUBU

Gomina ipinlẹ Ekoo, Babajide Sanwo-Olu ti banujẹ nitori iku olori awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Eko tẹlẹri, Alaaji Rafiu Tinubu, ẹni to jade laye lẹni ọdun marundinlọgọrin (75) lọjọ Wẹside ana lẹyin aisan ranpẹ, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Gboyega Akọṣile fi sita lo ti ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi ẹni to fara jin fun ipinlẹ naa, paapaa awọn oṣiṣẹ patapata, idi ni yii to fi sọ pe adanu nla lo jẹ fun ijọba ipinlẹ naa, paapaa orilẹ-ede Naijiria.

O ni, o ṣeni laanu pe asiko tijọba ipinlẹ naa nilo rẹ ju re e, lati gba ninu awọn ọgbọn ati iriri ẹ fun idagbasoke gan an niku wọle wẹrẹ muu lọ, to si tun jẹ ko ye gbogbo agbaye pe titi lai lawọn yoo maa fi ṣeanti ẹ.

Bakan naa lo sọ pe ọdun mẹrindinlọgbọn ti oloogbe naa fi ṣiṣẹ labẹ ijọba ipinlẹ Ekoo lo ni ipa rere, paapaa nigba to tun di olori awọn oṣiṣẹ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI