XENOPHOBIA: IKỌLU AWỌN SOUTH AFRIKA SI NAIJIRIA - ẸKUNRẸRẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 4, 2019

XENOPHOBIA: IKỌLU AWỌN SOUTH AFRIKA SI NAIJIRIA - ẸKUNRẸRẸ

Okun kii ho ruru ka wa ruru! Bayii ni ijọba apapọ ṣe n parọwa fawọn ọmọ Naijiria pe ki wọn ye kọlu awọn ileesẹ to jẹ ti orilẹde South Africa to wa ni Naijiria lati gbẹsan iṣekupani awọn ọmọ Naijiria lorilẹde naa.

Ijọba ni kikọlu awọn ileeṣẹ orilẹede South Africa ni Naijiria yoo ni ipa ti ko dara lara ọmọ Naijiria ju South Africa lọ.

Minisita fun iroyin ati aṣa, Alhaji Lai Mohammed sọ ninu atẹjade kan pe bawọn ọmọ Naijiria kan ti fi ibinu kọlu awọn ileeṣẹ to jẹ ti orilẹede South Africa lọjọ Iṣẹgun ku diẹ kaato.

Lai Mohammed ni awọn ọmọ Naijiria ni oludokowo lawọn ileeṣẹ orilẹede South Africa, nitorinaa fifi ọwọ ara ẹni ṣera ẹni ni kawọn ọmọ Nigeria maa ba iru awọn ileeṣẹ bẹẹ jẹ.

Bakan naa ni minisita eto iroyin ati aṣa ni ọmọ Naijiria lo pọju ninu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ South Africa to wa ni Naijiria.

O fikun ọrọ rẹ pe awọn ọmọ Naijiria lo maa fori ko ju, ti awọn ileeṣẹ orilẹede South Africa ba di titi pa.

Minisita Aarẹ Muhammadu Buhari ti ran awọn aṣoju si aarẹ South Africa lati fi ẹdun ọkan rẹ han ati lati wa nnkan ṣe si ikọlu ati ikoriira awọn ọmọ Naijiria to n gbe ni South Africa.

O ni aarẹ ti sọ fun minisita ọrọ ilẹ okere, Geoffrey Onyeama pe ko ranṣẹ pe aṣoju orilẹede South Africa ni Naijiria pe ko wa sọ tẹnu rẹ, bi o tilẹ jẹ pe aṣoju South Africa oun ti sọ pe ohun to n ṣẹlẹ kii ṣe ikoriira awọn ọmọ Naijiria.

Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu alako PDP ti kepe ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja lati pe ipade pajawiri lori ọrọ naa.

PDP bu ẹnu ẹtẹ lu ijọba Aarẹ Buhari pe ko tete ja ọrọ naa kunra, wọn ni o buru jai pe olu ileeṣẹ Naijiria to wa nilẹ South Africa tun kọ ẹyin si awọn ọmọ Naijiria to sa lọ sibi.


Osinbajo, Ekweremadukorò ojú sí ìkọlù South Africa

Igbakeji Aarẹ orilẹede Naijiria ki kesi awọn adari lorilẹede South-Africa pẹlu ibanujẹ ọkan lati dẹkun ipaniyan nitori ẹya to n lọ lọwọ lorilẹede South Africa.

Osinbajo lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni ipinlẹ Kano, sọ wi pe o lodi si igbelarugẹ ẹto ọmọniyan ti awọn adari ilẹ South Africa ja fun ni igba aye wọn.

O ni oun to buru jai ni lati kọju ija si awọn ọmọ Naijiria ti wọn wa ni South Africa bayii, nitori pe Naijiria pẹlu awọn to ja fun ominiran ilẹ naa lọwọ awọn amunisẹru.

Bẹẹ lo wa kesi ijọba orilẹede naa lati dide ati lati wa wọrọkọ fi sada lori ipaniyan naa ki oun gbogbo le pada si ipo.

'Naijiria gbọdọ̀ kọ ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú SouthAfrica '

Bakan naa, Igbakeji Aarẹ Ile igbimọ Asofin to kọja, Ike Ikeremadu ti kesi ijọba orilẹede Naijiria lati jawọ ninu gbogbo irẹpọ pẹlu orilẹede South Africa, titi ipaniyan awọn ọmọ Naijiria lorilẹede naa yoo fi dopin.

Ikeremadu ni o seni laanu pe ijọba orilẹede South Africa fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ipaniyan to n waye naa, lo se di ohun to n la ẹmi ọpọlọpọ eniyan lọ.

O wa kesi ijọba Naijiria lati ri wi pe ijọba ilẹ South Africa da gbogbo ikolọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn bajẹ pada, bakan naa ni ki wọn fi imu awọn aseka yii fọn fere.

Ike Ekeremadu naa parọwa si Ajọ isọkan Ilẹ Afirika, Africa Union lati da si ọrọ naa, ki o to di gbọnmi si, omi o to laarin orilẹede mejeeji.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI