SIEGO TAWỌN ỌLỌPAA N WA L'EKOO FOJU HAN, WỌN LOO DI IBẸRU FAWỌN ỌLỌPAA LATI MU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 5, 2019

SIEGO TAWỌN ỌLỌPAA N WA L'EKOO FOJU HAN, WỌN LOO DI IBẸRU FAWỌN ỌLỌPAA LATI MU

Bo tilẹ jẹ pe alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Bala Elkana ko tii sọ nnkankan titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan, ṣugbọn sibẹ, iyalẹnu lọrọ naa ṣi n jẹ fun ọpọ awọn to gbọ pe ẹni tawọn ọlọpaa kede loṣu kinni ọdun yi pe wọn n wa ni wọn tun forukọ rẹ sinu igbimọ ti yoo tukọ igbimọ ẹgbẹ onimọto ti wọn ṣẹṣẹ yan.

Mustapha Adekunle tọpọ awọn eeyan mọ si Siego lọkunrin naa ti Kọmiṣana ọlọpaa ana nipinlẹ Ekoo, Imohimi Edgar kede pe awọn n wa latari bo ṣe pẹluu awọn to wa nibi ti wọn ti da ipolongo idibo ẹgbẹ oṣelu APC ru l'Ekoo, ati pe o wa lara awọn to gun MC Oluọmọ lọbẹ.

Yatọ si eyi, wọn loun gan an lo lewaju bi ipolongo naa ṣe daru lọjọ naa, nibi tawọn oniroyin meji ti fara gba ibọn.

A gbọ pe oruko Siego gan an lo wa loke ninu awọn igbimọ awọn awakọ ti ẹgbẹ Roodu, iyẹn National Union of Road Transport Workers, eyi ti Ọgbẹni Musiliu Akinsanya tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ jẹ alaga ẹ.

Latigba ti wọn ti fi orukọ awọn ti yoo wa ninu igbimọ naa sita la gbọ pe awọn eeyan ti n woye boya awọn ọlọpaa yoo gbe igbesẹ lati lọọ mu ọkunrin naa, nitori ta a gbọ pe o ti foju han, ṣugbọn ti wọn ni awọn ọlọpaa ko sọ nnkankan.

AWIKONKO gbọ pe akọroyin Oloyinbo kan ti ileeṣẹ iwe iroyin Punch fi atẹjiṣẹ ori aago ranṣẹ si alukoro, ṣugbọn ti ko esi atẹjiṣẹ naa pada, yatọ si pe ko gbe foonu lati dahun ibeere. Idi ni yii tawọn kan fi n sọ pe ọrọ naa ti di ti oṣelu, tori pe awọn to wa lẹyin Siego lagbara ju awọn ọlọpaa lọ, ko si si nnkan ti wọn le ṣe fun un.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI