NITORI ẸSUN GBAJUẸ, PUROFẸSỌ FASITI FOJU BALE ẸJỌ L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSaturday, September 7, 2019

NITORI ẸSUN GBAJUẸ, PUROFẸSỌ FASITI FOJU BALE ẸJỌ L'EKOO

Lọjọru Wẹside to kọja yi ni ẹsẹ ko gbero nile ẹjọ giga kan to fikale sagbegbe Ikoyi niluu Ekoo lati wo oju baba agba kan to jẹ Purofẹsọ ni fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ to wa n'Ile-Ifẹ, ẹni ti wọn loo lu jibiti owo oni aimọye miliọnu naira.

 
A gbọ pe ajọ kan ti Purofẹsọ naa, Charles Jide-Oni da silẹ, eyi ti wọn lo fi n gba owo lọna aitọ lọwọ awọn onibaara rẹ ki aṣiri rẹ too pada tu.

 
Lara awọn ti Charles lu ni jibiti la gbọ pe wọn gbe ẹjọ rẹ lọ siwaju awọn ajọ EFCC, ko too di pe awọn yẹn bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn, ti wọn si ri i pe loootọ ni, paapaa nigba ti wọn tun ni ko le dahun awọn ibeere kọọkan ti wọn n bii.

 
Yatọ si Jide-Oni, a gbọ pe awọn ajọ EFCC naa tun foju awọn min in naa balẹ ẹjọ latari ẹsun jibiti ti wọn fi kan wọn niwaju Onidajọ Nicholas Oweibo tile ẹjọ ẹkun ilẹ Yoruba.

 
Awọn min in ti wọn tun foju wọn balẹ ẹjọ naa pẹluu ni; Ọlalẹyẹ Kọlapọ, Madukife Ifeanyi Azuka, Fatanmi Yinka Sunday, Adebayọ Bọlaji Adeyinka, Adeleke Peter ati Adebọwale Fadairo.

 
Awọn yooku ni; Oyewunmi Tolulọpẹ Michael, Bello Ayọade Jalal Arikalam, Owolabi Toheeb Tolulọpẹ, Abdullahi Abdulazeez Oluwatobi, Temitọpẹ Fatolu ati Adeṣina Adewale.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI