ARẸWA ỌLỌMỌGE YA WERE LỌSAN GANGAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, October 14, 2019

ARẸWA ỌLỌMỌGE YA WERE LỌSAN GANGAN

Ṣe lọrọ di boolọ o yago lọna laarọ oni Mọnde nigba ti wọn sọ pe ọlọmọge Arẹwa kan deede ya were, to si fẹ maa bu awọn eeyan jẹ, ṣugbọn ti wọn sa fun un.

Gẹgẹ bi awọn to fiṣẹlẹ naa to AWIKONKO leti ṣe sọ, wọn ni agbegbe kan ti wọn pe ni Rumuokwuta niluu Portharcourt, ipinlẹ Rivers niṣẹlẹ naa ti waye ni nnkan bi aago mẹsan an.

Wọn ni ode faaji alẹ tawọn to gbafẹ maa n lọ, iyẹn Night Clubni ọlọmọge naa ti n bọ, ko too di pe aisan naa kọluu lojiji lẹgbẹ opopona, eyi to ko ibẹrubojo sọkan awọn to wa nitosi.

 
Bo tilẹ jẹ pe ko tii ṣeni to le sọ nipa nnkan to ṣofun fa were to kọlu obinrin ti a ko tii mọrukọ rẹ dasiko ti ṣakojọpọ iroyin yi tan, ṣugbọn bẹ o ba gbagbe, laipẹ yi lawọn eeyan pariwo sita nipa ipakupa ti wọn n pawọn ọlọmọge ni otẹẹli kaakiri ipinlẹ naa, eyi to mu kawọn kan maa sọ pe boya ọna ara ti wọn tun fẹ maa gba re e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI