ỌRỌ NLA: TỌKỌ TIYAWO FI ỌMỌ WỌN RỌPO GBESE LỌSIBITU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, October 14, 2019

ỌRỌ NLA: TỌKỌ TIYAWO FI ỌMỌ WỌN RỌPO GBESE LỌSIBITU

Titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan lawọn tọkọ tiyawo kan ko tii yọju lati wo ipo ti ọmọ wọn ti wọn fi silẹ lọsibitu wa, latari bi wọn ṣe na papa bora latari gbese ti wọn sọ pe wọn ko ri san.

A gbọ pe o ti to ọsẹ mẹfa gbako bayii, ti Ọgbẹni Destiny Uregha ti mu iyawo rẹ salọ kuro ni ọsibitu naa, lẹyin owo ẹgbẹrun lọna aadọjọ din diẹ (139,000) ti wọn kọ fun wọn pe ki wọn lọọ wa wa, ṣugbọn ti wọn ko rii, iyẹn ọsibitu aladani kan  to wa niluu Sapẹlẹ, ipinlẹ Delta.

Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, wọn ni oṣu to lọ lohun ni iyawo Destiny bimọ obinrin, ti wọn si sọ ọ ni orukọ (Deborah), ko pẹ la gbọ pe ọmọ naa bẹrẹ aisan, ti wọn si n gbe e kaakiri ọsibitu lati ṣe iṣẹ abẹ fun un. Ko pẹ la gbọ pe ẹnikan juwe ọsibitu yi ta a forukọ bo laṣiri fun wọn pe ki wọn lọ sibẹ.

AWIKONKO gbọ pe owo yi ni wọn kọ fun tọkọ tiyawo naa pe wọn yoo san fun iṣẹ abẹ, ta a si gbọ pe ẹgbẹrun lọna ogoji naira ni wọn ko silẹ pe ki wọn fi maa ba iṣẹ abẹ naa lọ, ti wọn si gba a lọwọ wọn.

Wọn ni lẹyin iṣẹ abẹ yi ni ọkọ sọ fun iyawo rẹ pe ko sii tawọn yoo ti ri ọwọ naa san, bawọn ko ba fi kun irin ẹsẹ wọn, ati pe ko si nnkan ti yoo ṣe ọmọ wón, bawọn ba fi duro. Bo ṣe lọ re e, ti ko pada yọju tilẹ ọjọ naa fi ṣuu.

Irọlẹ ọjọ keji la gbọ pe iyaw Deborah sọ pe oun fẹẹ lọ ran nnkan toun yoo lo, ti wọn si ni alọ rẹ ni wọn ri, ko sẹni to ri apadabọ rẹ, ko da ti wọn sọ pe ko sẹni to ri wọn layika rara, iyẹn lati bi ọsẹ mẹfa titi dasiko yi.

Gbogbo akitiyan lati ri awọn mejeeji la gbọ pe o ṣi n ja si pabo dasiko yi, ti wọn si lawọn alaṣẹ ọsibitu naa ni wọn n tọju ọmó yi latigba naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI