AṢIRI IKU TO PA ALAGBA L'OGBOMỌṢỌ, IJAPA TO DAGBA JU LAGBAYE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 4, 2019

AṢIRI IKU TO PA ALAGBA L'OGBOMỌṢỌ, IJAPA TO DAGBA JU LAGBAYE

Ko tii sibi ti iroyin iku Ijapa ti wọn loo dagba ju lagbaye, eyi ti wọn n pe ni Alàgbà ko tii tan de lorilẹ-ede Naijiria, ati lagbaye, tori pe ironu lo ko ba awọn kan ti wọn ṣi n nifẹ sii lati ṣalabapade rẹ.

No photo description available. 
Ana tii ṣe Tọside la gbọ pe Ijapa naa, iyẹn Alagba jade laye lẹni ọdun ọọdunrun ati mẹrinlelogoji (344years) lẹyin aisan rampẹ.

Ohun ti a gbọ ni pe o ti le loṣu mloo kan bayii ti Alagba ti wa lori idubulẹ aisan, ti wọn si ti na aimọye owo lee lori, ṣugbọn ti ẹlẹmi pada gba a kuro lọwọ wọn. Aisan ọojọ ogbo ni wọn loo pada gba ẹmi Alagba.
Amugbalẹgbẹ Ṣọun tiluu Ogbomọṣọ, Ọba Ọladunni Oyewumi, iyẹn Toyin Ajamu lo firoyin naa sita lati jẹ kawọn eeyan mọ pe Alagba tawọn eeyan fẹran lati maa wo ti jade laye, to si ti ko ironu ba gbogbo Aafin.

Image may contain: one or more people, outdoor and nature 
Fawọn ti ko ba mọ, Ọba Oyewumi lo jẹ ki Alagba jẹ gbajumọ fawọn eeyan, latari itọju ara ọtọ to n fun un, to si tun pese ibi irọrun fun lati maa gbe, ko da, ti wọn ni Kabiyesi fẹran lati maa ba a ṣere ni gbogbo igba.

AWIKONKO gbọ pe ko si ipinu kankan lati sin Alagba lasiko yi, nitori ti wọn fẹẹ pa a mọ fun eto igbafẹ lati maa fi pawo wọle fun ilu naa.

Image may contain: grass, outdoor and nature 
Kaakiri agbaye ni wọn ti n lọọ wo Ijapa naa, ti wọn si tun n ba a ya fọto.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI