IJỌBA WO ILE AṢẸWO, LAWỌN AṢẸWO BA BU SẸKUN NITA GBANGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 4, 2019

IJỌBA WO ILE AṢẸWO, LAWỌN AṢẸWO BA BU SẸKUN NITA GBANGBA

Ọrọ buruku toun tẹrin nigba tijọba ipinlẹ Borno paṣẹ ki wọn wo ile aṣẹwo kan ti wọn lawọn eeyan fẹran lati maa lọ, eyi to wa niluu Maiduguri.

No photo description available. 
Bi ẹlẹkun ṣe n sunkun, bẹẹ ni ẹlẹrin n rẹrin, pẹluu bawọn aṣẹwo ti wọn ti sọ ibẹ di ile wọn ṣe bu sẹkun nita gbangba, tawọn kan si n fi wọn ṣẹlẹya.

Image may contain: sky and outdoor 
Kii ṣe pe ijọba deede paṣẹ pe ki wọn wo ile aṣẹwo naa lulẹ, bi ko ṣe olobo kan to ta wọn pe ibẹ lawọn ọdaran ti n pade ju lati ṣepade, ti wọn si loo gbajumọ daadaa, ko da, ti wọn lawọn ọtọkulu naa n de bẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI