MI O ṢEPADE PẸLU GOMINA ABIỌDUN NITORI AWỌN KỌMIṢANA RẸ - GBENGA DANIEL PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, October 19, 2019

MI O ṢEPADE PẸLU GOMINA ABIỌDUN NITORI AWỌN KỌMIṢANA RẸ - GBENGA DANIEL PARIWO SITA

Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ogun, Ọtunba Gbenga Daniel ti sọrọ, o ni ipade toun ṣe pẹluu Gomina Dapọ Abiọdun laipẹ yi kii ṣe lori ipo awọn kọmiṣana ti yoo ba a ṣiṣẹ papọ ni saa iṣakoso rẹ.

Ọtunba Gbenga Daniel lo sọrọ naa laipẹ yi niluu Abẹokuta lasiko to lọ ṣabẹwo si Gomina Abiọdun ni ọfiisi rẹ to wa ni Oke-Mọsan laipẹ yii, iyẹn lasiko tawọn oniroyin n beere ọrọ lọwọ rẹ.

O ni abẹwo lasan loun wa a ṣe pẹluu Gomina Abiọdun, toun si tun gba a lamọnran lori awọn ọna to le gba fi ṣe aṣeyọri ninu ijọba rẹ.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Gẹgẹ bi mo ṣe sọ tẹlẹ, mo kan wa a ki Gomina lasan ni. A si fọrọjomitoro ọrọ lori awọn nnkan to pọ diẹ. Mo si le fi daa yin loju pe kii ṣe ọrọ ipo kọmiṣana ni mo ba wa, ko ti ẹ si lara awọn nnkan ti a sọrọ le lori rara.

"Awọn eeyan gbọdọ mọ pe Dapọ kii ṣe ẹni to maa n kanju ṣe nnkan, ẹni to farabalẹ pẹluu imọ ni, to si tun jẹ pe oniṣowo to mọ awọn eeyan ni. Ọkan mi balẹ wipe yoo ṣe daadaa.

"Gẹgẹ bi ẹ ṣe mọ pe lati bi ọdun mẹjọ le diẹ ṣeyin ni mi o ti debi yi mọ, mo si rii pe iru awọn eeyan bi Gomina Dapọ Abiọdun kii ẹni ti mi o gbọdọ ma wa a ki, ki n si tun gba a nimọnran wipe a nifẹ awọn nnkan to n ṣe.

"Gomina ti n ṣi awọn ilẹkun tuntun, atawọn iriri igbalode. O si dun mọ mi ninu wipe o duro lori awọn ileri ẹ. Inu mi dun wi pe a n tẹsiwaju."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI