ỌKAN MI BALẸ LORI GOMINA DAPỌ ABIỌDUN - ALAGA ẸGBẸ OṢELU PDP NIPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, October 19, 2019

ỌKAN MI BALẸ LORI GOMINA DAPỌ ABIỌDUN - ALAGA ẸGBẸ OṢELU PDP NIPINLẸ OGUN

Alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Bayọ Dayọ ti sọ pe ọkan oun balẹ lori Gomina Dapọ Abiọdun, ati pe oun nigbagbọ pe eleti gbaroye to ko gbogbo eeyan mọra ni.

Onimọ-ẹrọ Bayọ Dayọ lo sọrọ naa lasiko to ṣabẹwo si Gomina Dapọ Abiọdun nileeṣẹ Gomina to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta laipẹ yi, nibẹ lo ti sọ pe oun fun Gomina Abiọdun ọgọrun maaki pe yoo ṣe daadaa ju ijọba to kọja lọ.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Ipinlẹ Ogun la wa yi, ọmọ Ogun si ni mi, to si tun jẹ pe Gomina ipinlẹ Ogun ni Dapọ Abiọdun. Eleyi yatọ si Gomina ana, ibikunle Amosun ti ko fẹẹ ri ẹnikankan soju rara, paapaa awọn ti ko ba si ninu ẹgbẹ oṣelu rẹ. Gomina ni Dapọ Abiọdun ti mo ti mọ fun ọpọlọpọ ọdun, to si mọ nnkan to n ṣe.

"Baba wa Ṣẹgun Ọṣọba ti jẹ Gomina ipinlẹ yi ri. Mo ni ninu ẹgbẹ NRC, toun si wa ninu ẹgbẹ SDP. Ọṣọba sọ fun wa nigba naa pe Gomina ipinlẹ Ogun loun, oun kii ṣe Gomina ẹgbẹ oṣelu SDP, ọpọ nnkan lo n ṣe fawọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji yi. O jẹ nnkan ti ko bojumu rara fun iṣakoso ọdun mẹjọ laigba awọn ẹgbẹ alatako laaye rara, itiju nla lo jẹ.

"Ṣugbọn ni bayii, a ti ni ọkunrin to mọ nnkan to n ṣe. Ọpọ awọn eeyan ni oju ti n kan lati maa ri eto iṣejọba awaarawa. Wọn ti n kanju ju, ko si yẹ ko ri bẹẹ,, nitori pe ẹni temi mọ yi yoo ṣe daradara lai si iyemeji nibẹ, bo tilẹ jẹ pe kii ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu wa.

"Latigba ti Gomina Abiọdun ti de ọfiisi rẹ, mi o tii wa a kii, idi ni yi ti mo fi wa. Mo wa lati wa dupẹ lọwọ ẹ fun awọn nnkan ribiribi to n ṣe e, nitori pe o n ṣe daadaa. Ọpọ ọrọ la jọ sọ nipa idagbasoke ipinlẹ Ogun, to si sọ awọn ipinu rẹ, eyi ti mo ri pe o dara pupọ.

"Inu mi dun si iru gomina ti a ni yi, ko da bi gomina ti tẹlẹ to jẹ pe nigba ti ẹ ko ba mọ nnkan to n ṣe, ẹ ko mọ nnkan to n ro, ti ko si fẹẹ gbọ nnkan ti ẹ fẹ sọ. Nitori pe mo wa ninu ẹgbẹ oṣelu alatako ko tunmọ si pe mi iṣẹ to fẹẹ ṣe ko dami loju. Mo fun un ni ọgọrun maaki wipe yoo ṣe daadaa."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI