MỌTO AWỌN OṢIṢẸ LASTMA GBOKITI LORI ERE ASAPAJUDE L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Saturday, October 19, 2019

MỌTO AWỌN OṢIṢẸ LASTMA GBOKITI LORI ERE ASAPAJUDE L'EKOO

Ọrọ buruku toun tẹrin lọjọ Wẹside to kọja yi nigba ti wọn sọ pe mọto awọn oṣiṣẹ to n da igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Ekoo, iyẹn LASTMA gbokiti lori ere, to si jẹ pe diẹ lo ku kawọn oṣiṣẹ naa ba ijamba naa lọ, ṣugbọn ti ori ko wọn yọ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni awakọ kan lo tapa si ofin irinna lagbegbe Onipanu, ti wọn loo mu kawọn oṣiṣẹ yi daa duro, ṣugbọn ti wọn ni kaka ko duro, ṣe lo na papa bora.

 
Idi ni yii ti wọn lawọn oṣiṣẹ LASTMA yi fi sare ko sinu mọto wọn lati le awakọ to tapa si ofin yi m, ṣugbọn to jẹ kayeefi nigba ti wọn maa de agbede meji Onipanu si Maryland ti wọn ni awakọ naa sa gba, to jẹ pe ṣe ni mọto wọn gbokiti lori ere.

 
Ọpẹlọpẹ awọn ẹlẹyinju aanu ti wọn sare debẹ lati doola ẹmi awọn oṣiṣẹ yi, boya wọn ki ba ti ba ijamba naa lọ.

 
Awọn araagbegbe naa la gbọ pe wọn pada ba wọn ti mọto wọn dide, ko too di pe wọn pada lọọ wa mọto nla kan to ba wọn wọọ kuro loju ọna. Ọpọ awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn, paapaa awọn to gbọ sii ni wọn n bu ẹnu atẹ lu bawọn oṣiṣẹ LASTMA ṣe n le awọn mọto nigba min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI