ỌLỌRUN BIṢỌỌBU OYEDEPO TUN GBỌNA ARA YỌ LORI AWỌN ỌMỌ IJỌ RẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, October 19, 2019

ỌLỌRUN BIṢỌỌBU OYEDEPO TUN GBỌNA ARA YỌ LORI AWỌN ỌMỌ IJỌ RẸ

Ọrọ inu bibeli kan to sọ pe 'Ma ṣe fọwọ kan ẹni ami ororo mi, ma si ṣe awọn wooli mi nibi' ni wọn loo lọ nibamu pẹluu bọwọ ṣe tẹ baale ile kan ti wọn fẹsun ijinigbe kan lọjọ Fraide ana.

AWIKONKO gbọ pe iyaale ile kan lo lọ sileewe awọn ọmọ re to wa lagbegbe D/Line niluu Port Harcourt lati lọ ko wọn lẹyin ti wọn jade ileewe, gẹgẹ bo ṣe ma lọ n ko wọn.

Obinrin naa re e
Lara awọn to fiṣẹlẹ naa to wa leti jẹ ko ye wa pe bi obinrin naa ṣe bọ sita lọgba ileewe naa pẹlu awọn ọmọ rẹ mẹta yi lo ri awakọ kan, to si daa duro wipe ko gbe awọn lọ sile.

Wọn ni bawọn ọmọ mẹta yi ṣe wọnu mọto naa tanto si ku ki iya wọn wọle ni wọn ni awakọ naa tan ina sọkọ rẹ, to si salọ pẹluu awọn ọmọ rẹ. Ṣe ni wọn ni ọrọ naa ṣe obinrin yi ni kayeefi, ti ko si kọkọ mọ nnkan to le ṣe, ṣugbọn loju ẹsẹ ni iye rẹ tun ti sọ pada, to si bẹrẹ sii pariwo iranlọwọ, ṣugbọn ti ẹpa ko boro mọ.

Image may contain: house and outdoor
Ileewe naa
Nibẹ ni wọn sọ pe obinrin naa ti bẹrẹ sii gbe ara rẹ sanlẹ, to si bẹrẹ sii gbadura kikan-kikan si Ọlọrun oludasilẹ ṣọọṣi rẹ, iyẹ, ṣọọṣi ti Biṣọọbu Oyedepo pe ko jẹri ara rẹ.

Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn la gbọ pe wọn n di obinrin naa mu, ti wọn si lawọn kan ti sare ranṣẹ pe awọn ọlọpaa lati fọrọ naa to wọn leti.

Si iyalẹnu wọn ni ibi ti obinrin naa ti n gbadura kikan-kikan, ko da, ti wọn lawọn eeyan n woo gẹgẹ bi ẹni to ti ya were lo ti gboju rẹ soke, to si ri mọto ti wọn fi ji awọn ọmọ rẹ gbe, ko da ti wọn sọ pe o tun ri awakọ naa ninu rẹ, ṣugbọn tawọn  ọmọ rẹ ko si ninu mọto naa.

Image may contain: 1 person, standing, sitting and shoes
Ọkan lara awọn ọmọ naa
Loju ẹsẹ ni wọn loo ti pariwo 'aleluya', to si tun pariwo pe oun ti ri ẹni to ji awọn ọmọ oun gbe lọ, ki oloju to o ṣẹ ẹ, awọn eeyan ti pe le ọkunrin na lori, ti wọn si bẹrẹ sii luu.

Asiko ti wọn fẹẹ dana sun un la gbọ pe awọn ọlọpaa ti wọn ti ranṣẹ pe yọju, ti wọn si gba a silẹ lọwọ wọn. Nigba ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo nipa ibi to ko awọn ọmọ naa, lo jẹwọ fun wọn pe oun ti lọọ ti wọn mọ ile oun.

Wọn ko beere ọrọ min in mọ lọwọ ẹ, ki wọn too tẹle e lọ sile ẹ, ti wọn si ko awọn ọmọ naa jade.

Image may contain: 2 people, people standing, car and outdoor
Mọto ọkunrin naa
 Teṣan ọlọpaa la gbọ pe ajinigbe naa ṣi wa dasiko ti a kọ iroyin yi tan.

Pupọ ninu awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni wọn n ba pbinrin naa yọ ayọ lori bo ṣe ri awọn ọmọ rẹ pada, ti wọn si lawọn eeyan tun n gbe oṣuba rabandẹ fun Ọlọrun Oyedepo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI