IDAGBASOKE ATI OPOPONA TO JA GEERE LO JẸ WA LOGUN - IJỌBA IPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, October 19, 2019

IDAGBASOKE ATI OPOPONA TO JA GEERE LO JẸ WA LOGUN - IJỌBA IPINLẸ OGUN

Igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele ti jẹ ko di mimọ pe lara awọn nnkan to ṣe pataki sawọn, to si tun jẹ awọn logun pupọ ni idagbasoke ati opopona to ja geere.

Onimọ-ẹrọ Salakọ-Oyedele lo sọrọ naa lasiko to n gba awọn ọmọ ẹgbẹ Musulumi kan, iyẹn Ahmadiya Muslim Society lalejo niluu Abẹokuta laipẹ yi.

Nibẹ lo ti sọ pe bawọn eeyan ba lọ kaakiri igboro, wọn yoo ṣakiyesi pe iṣẹ ti bẹrẹ ni pẹrẹu nitori pe aṣẹ ijọba apapọ lawọn n tẹle, eyi ti yoo faaye silẹ fawọn ileeṣẹ aladani to tun n ran ijọba lọwọ lati da sii.

O lawọn opopona to so awọn ilu kọọkan papọ ṣe papaki, nitori pe eyi gan an ni yoo jẹ ki eto ọrọ aje tubọ maa dagba bo ṣe yẹko dagba, ati lọna to yẹ.

Bẹẹ lo tun sọ pe owo ori okoowo to ba n wọle ni yoo tun jẹ iwuri fawọn ileeṣẹ yi, lati ṣe awọn nnkan to yẹ ki wọn ṣe, to si tun jẹ ko di mimọ pe Gomina Abiọdun ti n ṣiṣẹ tọsan-toru lati rii pe iṣẹ n lọ lori awọn opopona naa.

Siwaju sii lo tun sọ pe oju ọjọ asiko n ṣe idiwọ pupọ awọn agbaṣẹṣe to n ṣiṣẹ lọwọ, nitori pe ojoojumọ ni ojo n rọ, ati pe bi asiko yoo ba fi kasẹ nilẹ, iṣẹ naa yoo lọ geerege laisi idiwọ kankan.

Ṣaaju asiko yi ni Aarẹ ẹgbẹ naa, Alaaji Azeez Alatoye gbe oṣuba kare fun ijọba ipinlẹ Ogun lori akitiyan nipa idagbasoke ati eto ọrọ ajẹ ipinlẹ naa laari oṣu mẹrin ti wọn debẹ, to si tun gba a nimọnran lati ma ṣe gbọjẹgẹ lati tubọ ṣe ju bawọn eeyan ṣe le lero lọ.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI