ỌWỌ TẸ EMMANUEL ATI AANU PẸLU ORI OKU GBIGBẸ N'IJOUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 7, 2019

ỌWỌ TẸ EMMANUEL ATI AANU PẸLU ORI OKU GBIGBẸ N'IJOUN

"Iṣẹ eṣu ni, ẹ ṣaanu wa" lọrọ ẹbẹ ti wọn lo n tẹnu awọn ọdọmọkunrin meji tọjọ ori wọn ko tiii ju ọdun marundinlọgbọn lọ, Emmanuel Aro ati Anu Olofinju, awọn ti wọn fẹsun kan wi pe wọn ba ori oku gbigbẹ lọwọ wọn.

AWIKONKO gbọ pe ọmọ Yahoo lawọn eeyan kọkọ pe wọn pẹluu bi wọn ṣe n sọrọ wi pe oogun owo lawọn fẹẹ fi ori oku gbigbẹ naa ṣe.

Ọjọ kẹrin oṣu yi la gbọ pe ọwọ tẹ awọn meji naa lagbegbe Ijoun niluu Eggua lẹyin ti akara wọn tu sepo.

Ko too di pe ọwọ tẹ wọn, a gbọ pe ọmọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Amoo Bankọle ti lọ si teṣan ọlọpaa lati ta wọn lolobo pe oun n kofiri awọn meji yi nibi saare mama oun tawọn ṣẹṣẹ sin in laipẹ yi, o si ṣee ṣe ko jẹ pe wọn fẹẹ ji oku mama oun naa hu.

Idi ni yiii ti wọn lawọn ọlọpaa naa fi bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn, to si jẹ pe lọjọ tọwọ palaba wọn maa segi, bi wọn ṣe n jade nitẹku ti wọn ti lọọ ge ori oku yi, ọwọ ọlọpaa ni wọn ko si.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi ti jẹ ko di mimọ pe awọn eeyan naa ko ni pẹ ẹ foju bale ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI