AAYE ṢI SILẸ FAWỌN ADIGUNJALE LATI RI GOMINA ABIỌDUN TIPINLẸ OGUN – ALAGA ẸGBẸ OṢELU MEGA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 7, 2019

AAYE ṢI SILẸ FAWỌN ADIGUNJALE LATI RI GOMINA ABIỌDUN TIPINLẸ OGUN – ALAGA ẸGBẸ OṢELU MEGA

Alaga ẹgbẹ oṣelu Mega nipinlẹ Ogun, Alaaji Moshood Adeṣina, ti sọ pe ijọba ti Gomina Abiọdun n ṣe lọwọ nipinlẹ Ogun yi ti wa lori ipilẹ ti ko duro daadaa latari awọn to n ko mọra, ti wọn ko si le ran ijọba rẹ lọwọ rara, dibo bẹẹ, ipalara lo maa jẹ.

Adeṣina to tun jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ IPAC nipinlẹ Ogun lo sọrọ lasiko to n b’AWIKONKO sọrọ laipẹ yi niluu Abẹokuta lẹyin ipade ti alaga ẹgbẹ oṣelu Labour, to tun jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu agbarijọ gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Abayọmi Arabambi lọọ ṣepade pẹluu Gomina Dapọ Abiọdun nile iṣẹ ijọba to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Kọmureedi Arabambi lo ko awọn eeyan rẹ lẹyin lọọ ki Gomina Dapọ Abiọdun, nibi to ti fi ọkan Gomina balẹ wipe digbi loun wa lẹyin rẹ, toun si ṣetan lati ran an lọwọ ni gbogbo ọna to ba fẹ.

Ninu ọrọ Alaaji Adeṣina lo ti sọ pe “Mi o ri nnkan to dara si ipade naa rara, idi ni pe mi o figba kan ro o ri wipe Gomina Dapọ Abiọdun le wọ ara rẹ nilẹ to bẹẹyan, ko wa jokoo pẹluu iru eeyan buruku alagabagebe bii Arabambi.ipinlẹ Ogun yi la wa ti Abayọmi Arabambi fi ṣiṣẹ fun Gomina ana, Ibikunle Amosun lodi si Dapọ Abiọdun.

“Arabambi gbe Dapọ Abiọdun lọ si ile ẹjọ Tribunal, lati ibẹ ni wọn ti gba ile ẹjọ Kotẹmilọrun, iyẹn Appeal lọ niluu Ibadan, nibi ti ẹjó wọn ti pada fori sọgi. Awa kan wa to jẹ pe ẹgbẹ League of Registered Political Parties la fi n ṣagbatẹru ijọba, mọkandinlogun ni gbogbo ẹgbẹ oṣelu to parapọ lọdọ wa.

“Lasiko ti Arabambi lọ sọdọ Dapọ Abiọdun, ibi ti a ti n ṣepade la wa lọwọ lasiko naa, to si jẹ pe Gomina Dapọ Abiọdun la n ṣiṣẹ fun latigba ti ibo ti pari. Ti Dapọ Abiọdun ba sọ pe oun fẹẹ gbawọn eeyan lalejo, paapaa awọn agbaagba ninu ẹgbẹ oṣelu, ko yẹ ko jẹ pe Arabambi lo maa faaye silẹ fun lati gba lalejo. Abanijẹ lasan ni ọkunrin ti wọn n pe ni Arabambi jẹ, oun lo si n ba ijọba Dapọ Abiọdun jẹ latigba to ti wọle.

“A gbọ pe ẹgbẹ oṣelu ọgọrin lo ko lọ ba Gomina Abiọdun, nibo ni wọn ti ri ẹgbẹ oṣelu ọgọrin, ẹgbẹ oṣelu mọkandinlogoji la jọ wa nibi ti a ti ṣepade lasiko toun naa wa lọdọ Gomina Abiọdun, to si jẹ pe gbogbo wa la tọwọ bọwe pe lootọ la ṣepade. Bi ẹ lọọ wo o daadaa, gbogbo ẹgbẹ oṣelu to wa nipinlẹ Ogun ko to ọgọta, to si jẹ pe ninu idibo to kọja lọ, ẹgbẹ oṣelu mọkandinlogoji pere lo kopa lati fa Gomina wọn silẹ, nibo ni wọn ti ri awọn ẹgbẹ oṣelu ọgọrin to lọ ba Gomina Abiọdun.

“Bi Gomina Abiọdun ṣe fẹẹ ṣe ijọba ẹ lo ṣe n ṣe yẹn, o tun mọ si pe bi adigunjale gan an ba fẹẹ ri Gomina Abiọdun, aaye ṣi silẹ, nitori pe nnkan ti gbogbo awọn to ko mọra fi n jẹun niyẹn lati ori awọn Biyi, tori pe bi wọn ba ti gba owo lọwọ Gomina, wọn a le gba tiwọn naa nibẹ.

“Miliọnu marun un naira ni wọn gba lọwọ Gomina lọjọ ti wọn lọ, miliọnu meji naira ni Kọmureedi Arabambi ji ko sapo rẹ ninu owo naa, o fawọn alaga ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira, awọn ti wọn kan pe lati tẹlẹ wọn, iyẹn awọn ti wọn ko mọ nnkan to n lọ gba ẹgbẹrun lọna ọgbọn. Lẹyin eyi ni wọn tun lọọ pin miliọnu meji naira pẹluu awọn Biyi to jẹ amugbalẹgbẹ si Gomina.

“Ẹgbẹ oṣelu Labour gan an ko mọ pe wọn fẹẹ lọ ri Gomina, bi wọn ba fẹẹ lọ ri Gomina, gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ gboọdọ mọ si, ṣugbọn tori ijẹkujẹ wọn, wọn ko nii ṣe e. Wọn ko pe mi gẹgẹ bi igbakeji alaga, ibi ti a ti n ṣepade lọwọ la wa, ti a ti n gbọ.

“Bi Gomina Abiọdun ṣe fẹẹ ṣe ijọba rẹ lo ti n ṣe yẹn, ijọba awọn abanilorukọjẹ, ijọba gbajuẹ lo n ṣe, awọn ti ko le ran ijọba ẹ lọwọ lo fẹ maa gba mọra, nitori naa, ko si igbesẹ kankan ti a fẹẹ gbe nitori pe igba meloo ni ọdun mẹrin yoo fi pe, a n woran bayii.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI