IPINLẸ EKOO FẸẸ GBA'LEJO AWỌN ỌJỌGBỌN LAGBAYE L'Ọ́JỌ́BỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 6, 2019

IPINLẸ EKOO FẸẸ GBA'LEJO AWỌN ỌJỌGBỌN LAGBAYE L'Ọ́JỌ́BỌ


Ẹsẹ̀ kò ní í gbèrò ninu gbọ̀ngàn Freedom Park to wa ladugbo Broad, ipinlẹ Ekoo l'Ọjọbọ (Tọside), iyẹn ọjọ keje oṣu yi nibi ti awọn Ọjọgbọn atawọn Ọmọwe kaakiri agbaye yoo ti korajọ fun ti eto Yoruba Lakọtun to fẹẹ waye.

Gẹgẹ bi AWIKONKO ṣe gbọ, Ọjọgbọn Ọladele Orimoogunjẹ ti fasiti ipinlẹ Ekoo lo fẹẹ dawọn eeyan lẹkọọ nibi ipade Aṣa gbankọgbi naa to ma n waye lẹẹkan laarin oṣu mẹta.

Eto naa ti wọn n pe ni Yoruba Lakọtun, akanṣe iru nibi Lagos Books and Arts Festival, ikọkanlelogun iru ẹ la gbọ pe yoo bẹrẹ laago mejila ọsan, nibẹ si lawọn Ọjọgbọn bii Ọmọwe Oyeleke Odoje ti fasiti Ibadan; Oloye Gbemisọla Ayano atawọn min in yoo ti sọrọ.

Nigba to n b'AWIKONKO sọrọ laipẹ yi, Ọgbẹni Olutayọ Irantiọla to jẹ alakoso eto naa sọ pe inu oun dun lati ni ajọṣepọ pẹluu Lagos Books Arts and Festival, eyi ti igbimọ Relevant Arts ṣagbatẹru ẹ. O ni eto naa ti kọja oju tawọn eeyan le fi maa wo o, nitori pe eto agbaye ni.

Siwaju sii lo tun sọ pe inu dun wipe Aṣa ati iṣe Yoruba n gbilẹ si kaakiri ẹya Yoruba ni gbogbo agbaye, ati pe awọn yoo tubọ maa gbiyanjuu lati rii pe awọn eeyan n ri anfaani lati fojuriju pẹluu awọn Ọjọgbọ to n gbe Aṣa Yoruba ga.

O wa a muu ni aridaju pe eto tawọn fẹẹ ṣe l'Ọjọbọ yi lawọn yo fi sọri Ọloogbe Ọladẹjọ Okediji to jẹ gbajugba ati agba onkọwe, onkọtan nigba aye ẹ, ẹni to fi aye silẹ laipẹ yii.

Eto yi la gbọ pe wọn ti lo anfaani ẹ lati fi mọ riri awọn Ọjọgbọn bii Tunde Kelani, Mama Nike Okundaye; Oluṣesan Ajewole, Ọjọgbọn Taiwo Olunlade, Arabinrin Nike Adesanya, Kẹhinde Adepegba; Ayọ Okedokun atawọn min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI