AFURASI ỌMỌ YAHOO MẸRIN BU SẸKUN NI KỌỌTU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 17, 2019

AFURASI ỌMỌ YAHOO MẸRIN BU SẸKUN NI KỌỌTU

Ọrọ buruku toun tẹrin nile ẹjọ giga to fikalẹ siluu Ilọrin nipinlẹ lọjọ Ẹti (Fraide) ọsẹ to kọja nigba ti wọn lawọn gendunkunrin mẹrin kan ti wọn ni wọn ko niṣẹ meji ju jibiti ori ayelujara, iyẹn Yahoo bu sẹkun lasiko ti ajọ EFCC to n gbogun ti jibiti ati inakuna fẹsun kan wọn.

 
A gbọ pe ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin lọwọ ajọ EFCC tẹ awọn gendekunrin naa, ti wọn pe orukọ wọn ni Chilaka Dickson, Abdulahi Abubakar, Ọlayiwọla Azeez ati Enoch Oluyọde, ti wọn si pada foju wọn bale ẹjọ lẹyin ọpọlọpọ iwadii wọn.

 
Nigba ti wọn n sọrọ lori ẹsun ti wọn fi kan wọn niwaju Onidajọ Mahmod Abdulgafar, AWIKONKO gbọ pe mẹta ninu awọn mẹrẹẹrin lo sọ pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, ti ọkan lara wọn si sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti wọn fi kan oun.

 
Eyi lo mu ki Onidajọ Mahmood sọ pe ki gbogbo wọnm ṣi lọ jẹgbadun diẹ lahamọ awọn EFCC, to mu ki wọn bu sẹkun pe afaimọ kawọn ma pada ṣẹwọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI