MI O LE GBAGBE ỌJỌ TI AYỌJURAN FẸẸ PA MI – YINKA AYEFẸLẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 17, 2019

MI O LE GBAGBE ỌJỌ TI AYỌJURAN FẸẸ PA MI – YINKA AYEFẸLẸ

Gbajugba onkọrin nni, Ọmọwe Yinka Joel Ayefẹlẹ, to tun jẹ oludasilẹ ileeṣẹ Fresh FM lorilẹ-ede Niajiria, ti sọ pe lara ọjọ toun ko le gbagbe nigbesi aye oun lọjọ toun lọọ ṣe ayọjuran.

Alẹ oni tii ṣe Aiku (Sande) ni ogbontarigi onkọrin agbaye naa tu aṣiri yi lori redio rẹ, Fresh FM to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lori eto rẹ to pe ni Ọpẹyẹmi.

Yinka Ayefẹlẹ sọ pe o ye keeyan maa dupẹ lọwọ Ọlọrun ni gbogbo igba ti wọn ba wa laye, paapaa lasiko ti wọn ba n ranti ọjọ ti wọn ki ba ti ku danu bi eera.

Nibẹ lo ti sọ pe oun ko le gbagbe ọjọ toun ko ba ti dẹni igbagbe, iyẹn lọjọ toun n gbọ ariwo iyun ninu igbo, eyi to sọ pe ẹni kan n ge igi lọwọ. O ni bi ẹni naa ṣe n ge igi yi lọwọ loun fẹẹ lọọ wo, gẹgẹ bi ayọjuran.

Ọmọwe Ayefẹlẹ to ni ipele kẹrin lòun wá nílé ẹ̀kọ́ alakọọbẹrẹ (Primary 4) nígbà náà sọ pe boun ṣe dẹ inu igbo naa, ko tii ju iṣẹju aaya (10seconds) mẹwaa toun gba abẹ igi kan loun gbọ ariwo wipe igi wo lulẹ, nigba toun yoo si fi boju wẹyin, loun rii wipe igi toun gba abẹ rẹ kọja lo wo lulẹ.

O ni bi ki i ba a ṣe pe Ọlọrun wa lẹyin oun ni, o ṣee ṣe ko jẹ pe igi naa ni yoo ti ṣeku pa oun danu. Loju ẹsẹ lo sọ pe oun bu sẹkun, ati pe ori ẹkun yi loun wa ti ẹni to n ge igi lọwọ naa fi sare wa a ba oun lati beere nnkan to n pa oun lẹkun.

Gbajumọ onkọrin to ṣe ayẹyẹ ikomọjade awọn ọmọ ẹ niluu Ibadan laipẹ yi jẹ ko di mimọ pe ohun to wa lọkan ẹni to n ge igi naa ni pe boya lara igi toun n ge lọwọ lo wo lu oun, ṣugbọn toun sọ fun un pe boun ṣe kọja tan ni igi naa wo.

O lẹsẹkẹ loun ti n pariwo wi pe oun fẹẹ pada sile, nitori pe bi ki i ba a ṣe oore ọfẹ Ọlọrun, o ṣee ṣe ki igi naa wo pa oun pẹluu ayanjuran lọdun naa lọhun.

Siwaju sii lo tun jẹ ko di mimọ pe lọjọ kan loun tun lọọ gbe dooro kan, iyẹn peeli 32, to loun fẹẹ fi fa omi ninu kọnga laimọ pe kinni naa lagbara ju oun lọ.

O sọ pe diẹ lo ku koun jabọ sinu kọnga, ṣugbọn to jẹ pe ideri kọnga naa lo da oun duro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI