GBOGBO NNKAN TI A BA NI LA MAA FI SATILEYIN FUN VGN - IJOBA IPINLE OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, November 17, 2019

GBOGBO NNKAN TI A BA NI LA MAA FI SATILEYIN FUN VGN - IJOBA IPINLE OGUN


Gomina ipinle Ogun, Omoba Dapo Abiodun ti so pe gbogbo nnkan tawon ba ni lawon yoo fi satileyin fun egbe alaabo Fijilante, iyen Vigilante Group of Nigeria nipinle naa, lati le je ki ise eto aabo tubo ba ti igbalode mu.

Laipe yi ni Gomina Abiodun seleri naa ni nibi asekagba ti idanilekoo olojo merin ti egbe Fijilante se fawon eeyan won, eyi to waye ninu ogba ikekoo tawon olopaa, iyen Police Training College to wa ni Iperu.

Nibe lo ti so pe gbogbo ise ribiribi ti egbe naa n se nipa eto aabo lawon n ri, ti ko si see gboju fo da, idi ni yi to fi lawon ti setan lati se iranlowo to ba wa ni ikapa ijoba fun won.

Gomina Abiodun ti Onorebu Kunle Sobukola to n soju agbegbe Ikenne nile igbimo asofin ipinle Ogun soju fun nibi asekagba naa so pe egbe Fijilante yi ni won n satileyin fun ijoba lori eto aabo, idi ni yi tawon fi gbodo se iranlowo fun won. 

Bakan naa lo wa a gba awon araalu  nimonran wipe kawon naa dide lati se iranlowo to ba ye fun awon Fijilante nitori pe awon ni won sunmo won, ti won si tun mo bo se n lo lawujo. 

Nibe ni won ti fun ijoba ipinle Ogun ni aami eye koriya, fun igbega ipinle naa to n lo lowo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI