ỌWỌ TẸ TỌBA, AFURASI ADIGUNJALE NI FUNAAB - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


https://haxbyq.com/mario?h=waWQiOjExNDYwMDIsInNpZCI6MTE4NDA4MCwid2lkIjo0MjE1NzYsInNyYyI6Mn0=eyJ&si1=&si2=


Sunday, November 17, 2019

ỌWỌ TẸ TỌBA, AFURASI ADIGUNJALE NI FUNAAB


Kani kii ṣe pé àwọn ọlọpaa Harmony tó wà nítòsí ilé ẹ̀kọ́ fasiti tí ọgbin niluu Abẹ́òkúta tètè de ibi tọwọ tí tẹ gendekunrin kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Tọba ni, bóyá kí bá ti wá lajule ọrùn lásìkò tá a ṣakojọpọ ìròyìn yí lọ́wọ́.

Tọba là gbọ pé wọn fẹ̀sùn idigunjale kan lópin ọ̀sẹ̀ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ lo tán yí, ẹni tí wọn sọ pé ó ti pẹ tí wọn tí ń wá a láti mú.


Gẹgẹ bí àwọn tó fi ròyìn náà tó AWIKONKO létí ṣe sọ, wọn loo tí pé àwọn adigunjale tí máa ń dá wọn láàmú lágbègbè naa, pàápàá lásìkò tí wọn ba sọ pe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí lọọ sì kíláàsì.

A gbọ pé ọpọ ìgbà táwọn akẹ́kọ̀ọ́ bá ti lọ sí kíláàsì ni wọn làwọn igara ọlọ́ṣà tẹnikẹni kò mọ yóò gbà yàrá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ láti kó wọn ní ẹrú àti dúkìá wọn salọ.


Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn ti lọọ fọrọ náà tó àwọn ọlọpaa létí tí wọn sì ni wọn rí àṣeyọrí kankan ṣe lórí ẹ. 

Àárọ̀ kutu ni nnkan bí aago meje àná tíì ṣe Satide Abamẹta là gbọ pé ọwọ tẹ Tọba ilegbee àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn ń pè ní LATOYE 1, èyí tó wà ládùúgbò Oluwo-Keesin, Camp tó wà lopopona Alabata.

Loju ẹsẹ tọwọ tẹ ni wọn làwọn tó dáa mọ dáadáa tí bẹ̀rẹ̀ sii fẹ̀sùn kan án wípé olè gidi ni, to mú kí wọn bẹ̀rẹ̀ sii luu káàkiri gbogbo àgbègbè náà.

Lasiko ti wọn n dáná ìyá fún un lọ́wọ́ là gbọ pé àwọn ẹlẹyinju àánú tí ránṣẹ́ sáwọn ọlọpaa, tí kò sì pẹ táwọn ọlọpaa fi dé láti muu lọ sí teṣan wọn, níbi tó wà dasiko tá a ṣakojọpọ ìròyìn yí tán. 

Ipele kẹrin ni ẹka ikẹkọọ AGAD ni wọn sọ pé Tọba wá ní fasiti FUNAAB yí, tá a sì gbọ pé ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ láti mọ bóyá lootọ ni Tọba jẹ ọ̀daràn. 

Gbogbo akitiyan láti bá Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi tó jẹ́ agbẹnusọ fáwọn ọlọpaa sọrọ lọ ja si pàbó lásìkò tá a kọ ìròyìn yí tán.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI