IDI TAWỌN EEYAN ṢE RO PE MI O LE FUN OBINRIN LOYUN - YINKA AYEFẸLẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 2, 2019

IDI TAWỌN EEYAN ṢE RO PE MI O LE FUN OBINRIN LOYUN - YINKA AYEFẸLẸ

Gbajugbaja olorin ẹmi ti Juju nni, Ọmọwe Yinka Ayefẹlẹ ti sọrọ, o ni ọpọ awọn eeyan ti wọn mọ oun kaakiri agbaye ni wọn ti sọ ireti nu wipe oun kole lọmọ nile aye mọ latari ipo toun wa, bo tilẹ jẹ pe ọpọ igba loun funra oun ti gbiyanju lati ri ọmọ bi.

Yinka Ayefẹlẹ lo sọrọ naa laipẹ yi lasiko to n ba oniroyin kan sọrọ niluu Ibadan, nibẹ lo si ti jẹ ko di mimọ pe ko si ori oke adura toun ko lọ, bẹẹ ni ko si ọsibitu naa toun ko ti lọọ ṣayewọ ara oun, ṣugbọn to jẹ pe pabo lo ja si.

Ọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Ekiti naa sọ pe nigba toun gbọ wi pe iyawo oun ti loyun, o loun fẹẹ le ya were nitori pe ireti ti fẹẹ pin latari idaamu toun ti ṣe lati ri iyawo oun fun loyun, ṣugbọn ti gbogbo rẹ ti waa ja si ọpẹ bayii.

Nigba to n sọrọ lori idi pataki to ṣe tako awọn oniroyin to gbe iroyin nigba ti iyawo rẹ bi ibẹta, o sọ pe ko tii to asiko fun iyawo oun lati bimọ, to si jẹ pe awọn naa kere gidigidi nigba to maa bi wọn (premature), o ni ẹru lo ba oun nitori ọrọ awọn agba to sọ pe a kii sare kede iru awọn ọmọ bẹẹ.

Diẹ re e ninu awọn ọrọ rẹ:

"Bẹẹni, mọ kọkọ sọ pe iroyin naa ko ri bawọn eeyan ṣe n gbe kaakiri nigba ti iyawo mi bimọ. Ọpọ awọn eeyan ni wọn n sọrọ lori rẹ nitori pe awọn ọmọ naa kere jọjọ. Idi ni yi ti ẹru fi ba mi lati sare maa kede wọn sita. Mi o fẹ padanu wọn lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti mo ti duro, ati pe owe Yoruba kan lo sọ pe bi a ba sare kede ọmọ ti igbagbọ wa wipe yoo ku, o ṣee ṣe ki ọmọ naa pada ku.
 "Mo ni lati fi aṣiri naa pamọ laarin mọlẹbi mi digba ti wọn yoo fi dagba pẹluu ilera pipe. Idi ni yii ti mo fi sọ pe ko ri bẹẹ nigba ti iroyin naa jade sita. Ṣugbọn iyawo mi sọ fun mi pe ki n ma bẹru, nitori pe Ọlọrun to fun wa lawọn ọmọ naa yoo daabo rẹ bo wọn. Idi ẹ tun ni yii ti mo tun fi sọ pe kawọn eeyan ba mi kọrin ọpẹ ọmọ.
"O ṣoro lati fi aṣiri pamọ. Ọpọ awọn ta a jọ wa nidi iṣẹ iroyin ati igbohunsafẹfẹ lo mọ sii, ṣugbọn mo ni lati sọ fun wọn wipe ki wọn duro asiko to tọ lati kede sita. Mo gbiyanju gbogbo agbara mi lati pa iroyin naa mọ, mi o gbe aworan wọn sita. ọjọ kejidinlogun oṣu kinni ọdun yi la bi awọn ọmọ naa ni ọsibitu Holy Cross to wa ni USA.

"Mi o le sọ bo ṣe ri lọkan mi nigba ti a kọkọ lọọ ṣayẹwo oyun, paapaa nigba ti oyun naa pe oṣu mẹta gbako, ati oṣu mẹfa titi de oṣu kẹsan an nitori pe ṣisẹ-ntẹle ni, abi ki n sọ nipa igba to n rọbi lọwọ. Mo fẹẹ le ya were nigba ti mo kọkọ gbọ wipe iyawo mi ti loyun.

"Mi o kọkọ gbagbọ lẹyin ọpọlọpọ ayẹwo ati igbiyanju. Mi o mọ ẹni ti mo maa sọ fun, ṣugbọn in alẹ ọjọ to maa bimọ, mo ti ri i pe ibẹta ni wọn, nitori pe ọpọ igba la jọ lọ ya aworan oyun (scan). Mi o le sọ bi inu mi ṣe dun to lalẹ ọjọ naa nitori pe igbeyawo ọdun mejilelogun ni.
 
"Mi o kọ lati ni ibẹta, ko da, ko si nnkan to buro nibẹ bi mo ṣi bimọ de ogun, nitori pe mi o le sọ bi inu bi ṣe bajẹ to, atawọn nnkan ti mo la kọja lati lori wipe mo n wa ọmọ. Ko rọrun lati maa ti ori oke kan bọ si ori oke min in, ti mo n lọ lati ọsbitu kan bọ sibomin in lorilẹede yi ati loke okun, ti mo si n ṣe oriṣiriṣi ayẹwo.

"Ori aga ni Yinka Ayefẹlẹ wa, awọn eeyan ro wi pe mi o le fun obinrin loyun latari ipo ti mo wa, paapaa ti ọpa ẹyin mi to ti kan. Sibẹ, Oluwa bunkun mi pẹluu ọmọ mẹta lẹẹkan ṣoṣo."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI