Ẹ MA SALỌ KURO NI NIGERIA O – PETER OBI RAWỌ ẸBẸ SAWỌN ỌMỌ NAIJIRIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Saturday, November 2, 2019

Ẹ MA SALỌ KURO NI NIGERIA O – PETER OBI RAWỌ ẸBẸ SAWỌN ỌMỌ NAIJIRIA

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta - Gomina tẹlẹri nipinlẹ Anambra, Dọkitọ Peter Obi ti rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ orilẹede Naijiria wipe ki wọn ma ṣe pinu lati fi orilẹede wọn, Nigeria silẹ lasiko yi latari awọn nnkan to n ṣẹlẹ nipa bi eto ọrọ aje ko ṣe fi bẹẹ lọ deede.

Peter Obi lo sọrọ naa lọjọ Ẹti (Furaide) ana nibi ayẹyẹ ikẹkọọgboye awọn akẹkọọ ti ile ẹkọ giga (fasiti) Chrisland, eyi to wa lopopona Ajebọ niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun

O sọ pe loootọ ni ko sẹni ti ko mọ pe nnkan ko fi bẹẹ fararọ lorilẹede Naijiria, ati pe iru nnkan to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ bayii ko ṣẹṣẹ maa ṣẹlẹ, nitori naa, afi kawọn ọmọ Naijiria fi ara daa, nitori pe fungba diẹ ni.

Bẹẹ lo tẹsiwaju pe ọna kankan ṣoṣo tawọn ọdọ orilẹede yi le fi tete ri ọwọ mu ni lati maa ronu kọja nnkan ti ẹnikẹni le lero lọ nitori pe aye ta a wa lasiko yi ti jara gidi, to si n pe fun ironu ati agbekalẹ ọtun to le mu anfaani nla bawọn eeyan.

O ni ẹdun ọkan lo ma n jẹ foun bawọn akẹkọọ ṣe maa jade, to jẹ pe wọn ko nii ri iṣẹ ti wọn tori ẹ lọ sile ẹkọ, idi ni yii to fi sọ pe ijọba ko le pese gbogbo nnkan tan fawọn akẹkọọ, nitori naa awọn ni ki wọn ronu ọna min in ti wọn le gba fi ri ilọsiwaju ara wọn.

O ni ọna bi idagbasoke ọtun yoo ṣe de ba orilẹede Naijiria ni ki wọn maa wa, dipo wipe wọn nsalọ kuro lorilẹede yi lọ sibo min in, nitori toun ṣi nigbagbọ wipe Naijiria yoo dara laipẹ, ati pe oun ti gba awọn ọmọ oun lamọnran wipe wọn ko gbọdọ fi ilu yi silẹ lọ maa gbe ilu oniluu.

Nigba to n sọrọ lori ijọba rẹ fọdun mẹjọ, o ni lara awọn aṣeyọri toun ṣe ni pe oun ko jẹ oṣiṣẹ kankan lowo oṣu, owo ajẹẹlẹ ati owo ifẹhinti, nitori toun mọ pe nnkan ti wọn gbojule niyẹn, ati pe ẹri ọkan oun ko le jẹ koun fiya jẹ awọn eeyan to fi ibo gbe oun wọle.

Bakan na lo tun ni o yẹ ki oju ti awọn oloṣelu ti wọn n fiya jẹ awọn eeyan wọn, ati pe bawo lawọn eeyan yoo tun ṣe dibo yan Gomina to jẹ owo oṣu ọdun kan sipo lẹẹkeji, ati pe o yẹ kawọn eeyan naa ronu wọn wo gidigidi.

Nigba toun naa n sọrọ, Giwa ile ẹkọ Chrisland sọ pe oun ko le ṣai dupẹ lọwọ Ọlọrun to n jẹ ki ilọsiwaju maa de ba ile ẹkọ naa lojoojumọ, nitori pe nigba toun maa gba ipo Giwa yi lọjọ kinni oṣu kọkanla ọdun 2017, anfaani nla lo jẹ foun, to si jẹ pe gbogbo oke iṣoro ni Ọlọrun sọ di pẹtẹlẹ.

O ni kii ṣe ti wipe awọn meje pere lawọn to n kẹkọọ gboye, ṣugbọn awọn meje naa lo fitan tuntun balẹ nitori pe ṣe ni wọn kọ ẹkọ naa yọri, ti ko si sibi ti wọn ko ti le figagbaga pẹluu akẹgbẹ wọn lagbaye.

Bẹẹ lo ni lara awọn nnkan to maa n mu ori oun wu, to tun jẹ gẹgẹ bi aṣeyọri ni bi ajọ to n ṣabojuto eto ẹkọ lorilẹede Naijiria ṣe bu ọwọ lu awọn ẹka ikẹkọọ wọn gbogbo pẹluu ọgọrun maaki (100%).

Awọn akẹkọọ meje ni wọn kẹkọọ gboye, awọn naa ni Ayẹni Ọlaoluwa, Ṣomọrin Bolutifẹ, Alugo oluwatoyin, Ọladokun Grace, Eluagwule Ruth, Onemu Lauretta ati Etekebe Ifiok.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI