KAYEEFI NLA RE O: WỌN JI ỌMỌDUN KAN GBE NINU ṢỌỌṢI L'AKURẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 13, 2019

KAYEEFI NLA RE O: WỌN JI ỌMỌDUN KAN GBE NINU ṢỌỌṢI L'AKURẸ

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fọkan awọn araalu balẹ wipe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati ri ọmọdun kan, Gold Kọlawọle ti wọn ji gbe ninu ṣọọṣi kan niluu Akurẹ lọjọ Aiku Sande to kọja yi, sibẹ, kayeefi lọrọ naa ṣi n jẹ fun gbogbo awọn to gbọ nipa ẹ.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni ko tii ju ọsẹ meji lọ ti wọn ji iya arugbo ẹni ọdun marundinlaadọrun kan gbe ni Ṣọọṣi Deeper Life to wa niluu Akurẹ niroyin min in tun jade wipe wọn ji ọmọdun kan pere gbe, ti wọn ko si tii mọ ibi ti ọmọ naa wa dasiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan.

A gbọ pe iya ọmọ lo mu ọmọ rẹ yi lọ si Ṣọọṣi lọjọ naa, ti wọn si ni ko mọ bi ọmọ naa ṣe poora mọn gbogbo awọn eeyan to wa ninu Ṣọọṣi naa loju, to si jẹ pe ọmọ ti wọn n wa yi lo mu ki wọn tete pari isin lọjọ naa.

Ọgbẹni Fẹmi Joseph to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ lati ri ọmọ naa gba pada, ati pe oun nigbagbọ wipe awọn yoo ri i.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI