TẸGBỌN TABURO PA ABURO WỌN, ỌMỌ ỌSẸ KAN DANU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 7, 2019

TẸGBỌN TABURO PA ABURO WỌN, ỌMỌ ỌSẸ KAN DANU

Gbogbo origun mẹrin agbaye tiroyin naa tan de lọrọ naa ṣi n ṣe ni kayeefi dasiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan latari bi wọn ṣe sọ pe awọn tẹgbọn taburo kan fun ọmọ ti mama wọn ṣẹṣẹ bi lọrun, titi to fi jade laye.

Ohun to n jẹ iyalẹnu ni wọn tun ṣe lọọ gbe oku ọmọ naa pamọ sinu paali, to si jẹ pe alubami lawọn eeyan lu wọn nigba ti aṣiri wọn tu. Agbegbe Ofunwegbe to wa nijọba ibilẹ Ovia North-East, ipinlẹ Edo niṣẹlẹ naa ti waye lọjọ Iṣẹgun (Tusidee) to kọja yi.

 
Wọn ni ọmọdun mẹjọ lọmọdebinrin to jẹ ẹgbọn, ti aburo rẹ toun jẹ ọkunrin si jẹ ọmọdun mẹfa. Iya wọn la gbọ pe wipe o ṣẹṣẹ bimọ naa lọsẹ to kọja, ti wọn si ṣẹṣẹ sọ orukọ rẹ.

Ko tii ye ẹnikẹni lori idi tawọn ọmọ naa ṣe ṣeku pa aburo wọn yi.


 
Iya wọn la gbọ pe o figbe ta sita pe kawọn eeyan gba oun nitori pe awọn ọmọ toun bi ti lu ọmọ toun ṣẹṣẹ bi pa, ti wọn ti n gbiyanju lati ju oku rẹ nu. Ere lawọn eeyan kọkọ pe e ko too di pe wọn pada rii pe loootọ ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI