NITORI AKOTO, OṢIṢẸ TRACE LU ỌLỌKADA OPAY DAKU L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 19, 2019

NITORI AKOTO, OṢIṢẸ TRACE LU ỌLỌKADA OPAY DAKU L'ABẸOKUTA

Aheso lasan ni - Alukoro TRACE

Ṣe lọrọ di boolọ o yago lọna lagbegbe Ibara to wa niluu Abẹokuta l'Ọjọru Wẹside ọsẹ to kọja yi nigba ti wọn lawọn oṣiṣẹ ẹṣọ oju popona tipinlẹ Ogun, iyẹn TRACE lu ọlọkada Opay lalubami, tiyẹn si daku laarin titi, eyi to mu kawọn ẹgbẹ rẹ naa wọya ija pẹluu wọn.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni kii ṣe pe oṣiṣẹ TRACE ta a ko tii m'ọruko rẹ dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan dee de lu ọlọkada Opay naa, bi ko ṣe ti ẹsun to fi kan an wipe ero to gbe lẹyin ko de akoto sori gẹgẹ bi ofin ati ilana ti wọn gbe kalẹ fun wọn.

Awọn to fiṣẹlẹ naa to AWIKONKO leti jẹ ko ye wa pe ni nnkan bi aago meji ọsan niṣẹlẹ naa waye labẹ biriiji Ibara, to wa nitosi Panṣẹkẹ niluu Abẹokuta.

Wọn ni ina to maa n da awọn mọto duro lo da ọlọkada Opay naa atawọn mọto min in duro lọjọnaa, ọọkan ni wọn si ni oṣiṣẹ TRACE naa ti n wo ọlọkada naa lọọkan pẹlu ero lati muu.

Ṣugbọn nigba ti wọn ni oṣiṣẹ TRACE naa yoo fi debẹ, ina ti so pe kawọn mọto kọja, ori irin ni wọn ni TRACE yi ti fa ọkada naa mọn ọlọkada yi lọwọ, toun ati ero to gbe si ṣubu lulẹ, eyi ni wọn loo mu ki ọlọkada yi fibinu sọrọ pe ṣe o fẹẹ pa awọn danu ni.

Ọrọ naa ni wọn loo bi oṣiṣẹ TRACE naa ninu to fi bẹrẹ sii da igbaju bo ọlọkada Opay naa, ti wọn loo tun n fọ igi ọwọ rẹ to mu dani mọn ọn, titi to fi ṣubu lulẹ.

Ere la gbọ pe awọn tọrọ naa ṣoju wọn kọkọ pe e, afigba ti wọn rii pe ọlọkada naa ko min in mọ, awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn la gbọ pe wọn sare lọọ gbe omi, ti wọn daa le lori, lẹyin bi iṣẹju marun la gbọ pe o pada taji saye.

Lasiko ti won ni ọlọkada Opay yi daku silẹ, lawọn ọlọkada ẹgbẹ ẹ ti paaki lati gbẹsan, ti wọn si ni asiko ti wọn fẹẹ dana iya fun oṣiṣẹ TRACE naa lawọn yooku rẹ yọju, tọrọ naa si di isu ata yan an yan.

Ko pẹ ni wọn lawọn ọlọpaa de bẹ, ti wọn si bawọn yanju ọrọ naa. AWIKONKO gbọ pe kii ṣe akọkọ re e tawọn oṣiṣẹ TRACE yoo maa mu awọn ọlọkada Opay lori wipe awọn ero ti wọn n gbe kii fẹẹ lo akoto, to si jẹ pe ọpọ igba lawọn ọga awọn Opay yi ti maa n kilọ fun wọn pe ki wọn yee gbe ero ti ko ba ti gba lati lo akoto wọn.

Nigba to n b'AWIKONKO sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi to jẹ agbẹnusọ fun TRACE jẹ ko di mimọ pe ahesọ lasan lawọn eeyan n gbe kaakiri wipe TRACE lu ọlọkada, o ni ko si nnkan to jọ bẹẹ rara, wọn kan fẹẹ ba wọn lorukọ jẹ lasan ni.

Bẹẹ lo tun jẹ ko ye wa pe ọlọkada naa tapa si ofin ni, idi ni yii ti wọn fi ba a wi lori ẹṣẹ rẹ.

Ṣa o, ohun tawọn eeyan n sọ lori ọrọ ti Akinbiyi sọ ni pe tani eṣinṣin ko ba gbe lẹyin, bi kii ba a ṣe elegbo, ati pe awọn eeyan naa ko nii sọ eyi to n jẹ otitọ ọrọ nitori pe ohun to ṣoju awọn eeyan gedegbe  ni loun sọ pe ko ri bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI