KÉRÉSÌMESÌ: ALÁGA ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ UDP NIPINLẸ OGUN GBÁWỌN KRISTẸNI LÁMỌ̀NRÀN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


https://haxbyq.com/mario?h=waWQiOjExNDYwMDIsInNpZCI6MTE4NDA4MCwid2lkIjo0MjE1NzYsInNyYyI6Mn0=eyJ&si1=&si2=


Wednesday, December 25, 2019

KÉRÉSÌMESÌ: ALÁGA ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ UDP NIPINLẸ OGUN GBÁWỌN KRISTẸNI LÁMỌ̀NRÀN


Alága ẹgbẹ́ òṣèlú United Democratic Party, UDP nipinlẹ Ogun, Oloye Arábìnrin Jackie Adunni Kassim tí gba gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni lamọnran wípé kí wọn mú ìwà àti ìṣe Jésù Kristi ti wọn n ṣajọyọ lónìí ọdún Kérésìmesì lo, kí wọn sì túbọ̀ máa gbé orúkọ rẹ lárugẹ. 

Oloye Adunni Kassim lo sọ̀rọ̀ náà laipẹ yi niluu Ota ipinlẹ náà lásìkò tó ń báwọn ẹlẹ́ṣin Kristẹni ṣajọyọ ọjọ́ ìbí Jésù Olúwa, nibẹ náà lọ tún ti sọ pé kí wọn máa fi ìfẹ́ àti àlàáfíà tí Jésù polongo bá ara wọn lo. 

Ó ní ai sí ìfẹ́ àti ibadọrẹ laarin awọn èèyàn máa ń fà ifasẹyin àti ijakulẹ fún idagbasoke ìlú, pàápàá orílẹ̀ èdè, nítorí náà ni kò ṣe sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ bínú sí ara wọn. 

Bákan náà lo tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ wípé ai ni ibẹru Ọlọ́run lọ́kàn lo ń fà ìwà inúnibíni, èyí táwọn onigbagbọ gbọ́dọ̀ yọ kúrò nínú ìwà wọn, àti pé kí wọn gba àlàáfíà láàyè laarin ara wọn, àtàwọn alabagbe wọn. 

Bẹ́ẹ̀ lo tún tẹsiwaju pé kí wọn máa gbàdúrà fún oore ọ̀fẹ́ bí a ti ń wọnú ọdún 2020 lọ, èyí tó sọ pé ọdún náà yóò jẹ ọdún igbega. Àti pé káwọn ìjọba mú àwọn ìlérí wọn ṣe fáwọn aráàlú fún idagbasoke orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI