FALANTINE: NITORI OLOLUFẸ RẸ KỌ Ọ SILẸ LOJIJI, ỌMỌGE GBE MAJELE JẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 11, 2020

FALANTINE: NITORI OLOLUFẸ RẸ KỌ Ọ SILẸ LOJIJI, ỌMỌGE GBE MAJELE JẸ

Kayeefi lọrọ ọmọge kan t'ọjọ ori ẹ ko tii ju ọdun mejilelogun lọ ṣi n jẹ fun awọn to gbọ si iṣẹlẹ naa lori bi wọn ṣe lo o gbe majele jẹ lojiji.

 
Ọmọge ti a ko ti i mọ orukọ rẹ titi ta a fi kọ iroyin yii tan la gbọ pe ololufẹ rẹ kọ silẹ bi asiko ayẹyẹ ayajọ ololufẹ ṣe n wọle de, ti wọn si ni ibanujẹ lo jẹ fun un.

 
AWIKONKO gbọ pe ọdun kẹrin re e ti ọmọge yii ati ololufẹ rẹ to kọ ọ silẹ ti n ba ara wọn bọ, ko too di pe ipinya de laarin wọn lojiji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI