IGAHLO, ỌMỌ NAIJIRIA AKỌKỌ TI YOO KỌKỌ WỌ INU IWE ITAN TUNTUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSaturday, February 1, 2020

IGAHLO, ỌMỌ NAIJIRIA AKỌKỌ TI YOO KỌKỌ WỌ INU IWE ITAN TUNTUN

Ìtàn tuntun tí kò tíì ṣẹlẹ nínú ìtàn ère ìdárayá l'órílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni ọmọ ẹgbẹ́ agbabọọlu àgbà ọjẹ ilẹ̀ yìí (Super Eagles), ìyẹn Odion Ighalo tí fi balẹ báyìí, pẹ̀lú bo ṣé jẹ́ òun l'ọmọ orílẹ̀-èdè yìí tí yóò kọ́kọ́ gba bọọlu fún ẹgbẹ́ agbabọọlu Manchester United. 

Wọ́n loo tí pẹ tí oju ẹgbẹ́ agbabọọlu Manchester United ti wá l'ara Ighalo, tí wọn sì ti wá gbogbo ọ̀nà láti ra a, ṣùgbọ́n tí kò bọ sì í. 

Ní báyìí, a gbọ àdéhùn tí fẹẹ parí láàárín ẹgbẹ́ agbabọọlu Shanghai Shenhua tí Ighalo tí ń gba iwájú fún wọn pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbabọọlu Manchester United.

Òpin idije tó ń lọ lọ́wọ́ yìí là gbọ pé Ighalo, ọmọ ọgbọ́n ọdún náà yóò bẹ̀rẹ̀ sii gba bọọlu fún ikọ ẹgbẹ́ agbabọọlu Man U.

Fun àwọn tó bá mọ Ighalo dáadaa, ó ti gba goolu mẹtadinlogun wọlé nínú idije Premier League to tí kopa ni igba marundinlọgọta lásìkò tó fi wá ní ẹgbẹ́ agbabọọlu Watford.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI