AWỌN AṢIRI NLA TO TUN TU NINU IWADII IKU ỌKỌ OLOYUN RE O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 27, 2020

AWỌN AṢIRI NLA TO TUN TU NINU IWADII IKU ỌKỌ OLOYUN RE O

Ọpọ awọn aṣiri lo tun ti tu sita bayii lori iku Alaaji Fatai Yusuf ti ọpọ awọn eeyan mọ si Ọkọ Oloyun to jẹ alaṣẹ, apaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Oko-Oloyun Herbal Medical Center

Lara awọn aṣiri to tu sita naa ni bi wọn ṣe sọ pe awọn ọlọpaa ti ṣawari owo ti ko din ni miliọnu marundinlogoji (N35million) naira ninu apo ile ifowopamọ ọkọ ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ rẹ ti wọn pe orukọ rẹ ni Abbey.
A gbọ pe aṣiri owo kan t'awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ oloogbe naa ko jẹ lo tu si oloogbe naa lọwọ, to si paṣẹ wi pe k'awọn oluṣiro owo kan ba oun tọpinpin rẹ.

Laarọ kutu, ko to o di pe wọn pa Ọkọ Oloyun la gbọ pe ọfiisi oloogbe naa jona.

Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ jẹ ko ye wa pe oṣiṣẹ lasan ni Abbey jẹ n'igba to de ileeṣẹ Ọkọ Oloyun, ṣugbọn awọn iṣẹ ribiribi ti wọn lo o ṣe lo jẹ ki Ọkọ Oloyun sọ ọ di ẹni ti yoo maa mojuto bi ọja ṣe n wọle-jade.

Iwadii ṣi n lọ lọwọ bayii, ti a si fi da a yin loju pe gbogbo ẹ lẹ maa gbọ ni kulẹ-kulẹ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI