NǸKAN DE! CORONAVIRUS WỌ IPINLẸ EKO ATI ÒGÙN, IBẸRUBOJO B'ÁWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 28, 2020

NǸKAN DE! CORONAVIRUS WỌ IPINLẸ EKO ATI ÒGÙN, IBẸRUBOJO B'ÁWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ


Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, inú ibẹru-bojo ni gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà, pàápàá àwọn olùgbé ipinlẹ Eko ati Ogun wá báyìí, pẹ̀lú bí wọn ṣe kofiri aarun aṣekupani tó ń jà káàkiri àgbáyé lásìkò yìí, ìyẹn Coronavirus l'Ekoo.

Bẹ ó bá gbàgbé, ìlú Èkó yìí náà ni wọn ti kọkọ gburo aarun Ẹbola lọ́dún 2014, ìyẹn lásìkò ijọba Babatunde Faṣọla n'igba to burẹkẹ káàkiri àgbáyé.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ, ọjọ́ Mọnde tó kọjá yìí ni wọn sọ pé ọkùnrin kan tí wọn lo ó jé ọkàn lára àwọn oludamọran (consultant) fún ileeṣẹ Lafarge to ń ṣe simẹnti lorilẹ-ede Nàìjíríà de silu Eko. 

Ọjọ́ mẹta gbáko ni wọn ní ọkùnrin náà lo ni otẹẹli kán n'ilu Eko, kò tó o di pé ó lọ sí ileeṣẹ Lafarge náà tó wà ní Ewekoro, ipinlẹ Ogun fún ìpàdé. 

Kò pẹ tí wọn ní ọkùnrin ọmọ bibi orílẹ̀-èdè Italy naa ṣetan nibẹ là gbọ́ pé ó padà silu Eko, tó sì dubulẹ aisan. Ère ni wọn kọ́kọ́ pé afigba tí wọn rí í pé àìsàn náà fẹ ẹ yiwọ, tó mú kí wọn sáré gbé e lọ sí osibitu.

Osibitu yìí ni wọn l'awọn dókítà tí ṣàkíyèsí wí pé aarun Coronavirus lo wá lára rẹ, tí wọn sì sáré gbé e lọ sí ẹ̀ka iṣẹlẹ pajawiri tó ń rí sì ìṣẹ̀lẹ̀ yìí láti tètè bojuto ó kó tó o pẹ ju. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI