ILE AYE ASAN: GOMINA IPINLẸ AKWA IBOM FI POOSI ONI MILIỌNU MẸTALELAADỌRIN NAIRA SIN BABA RẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 27, 2020

ILE AYE ASAN: GOMINA IPINLẸ AKWA IBOM FI POOSI ONI MILIỌNU MẸTALELAADỌRIN NAIRA SIN BABA RẸ

Kayeefi ni bi Gomina ipinlẹ Akwa Ibom, Gomina Udom Emmanuel ṣe sinku baba rẹ pẹlu poosi olowo iyebiye ati saare olowo nla.

Miliọnu mẹtalelaadọrin (73million) naira ni wọn ra poosi to jẹ dayamọndi (diamond) ti wọn fi sin baba Udom Emmanuel.

Saare ta a gbọ pe wọn gbe oku naa si la gbọ pe wọn ṣe ni t'igbalode, iyẹn 3D tiles pẹlu miliọnu mẹjọ (8million) naira, ti a si gbọ pe ina mọna-mọna naa tun wa ninu saare yii.

Wakati mẹrinlelogun la gbọ pe ina yooo fi maa wa ninu saare yii, iyẹn lojoojumọ.

Awọn ina giloobu (Globe) ti wọn ṣe sinu saare naa la gbọ pe o ni ẹrọ amuletutu (Air Condition) ninu, ti yoo si maa mu inu saare naa tutu loore-koore.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI