BUHARI SO AGBADO MỌ IDI N'IWAJU AWỌN ỌMỌ NAIJIRIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 11, 2020

BUHARI SO AGBADO MỌ IDI N'IWAJU AWỌN ỌMỌ NAIJIRIA

Kete ti Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari fesi ni idahun si ikọlu ti awọn Boko Haram ṣe si awọn arinrin-ajo ti ko din ni ọgbọn ni ipinlẹ Borno.

Ikọlu yii waye ni ilu Auno, to jẹ opopona nla kan nipinlẹ Borno. Iroyin sọ pe 'ṣe ni awọn eeyan naa n sun lọwọ nigba ti ọkọ duro lọna lati sinmi lawọn alakatakiti agbebọn ba dana sun wọn.

Aarẹ Buhari sọ pe ikọlu to waye nirọlẹ ana jẹ eyi to ba ni lẹru pupọ ti ko si yẹ ko o waye. O tun wa sọ pe ijọba apapọ, ijọba ipinlẹ Borno ati gbogbo ọmọ Naijirà to fi mọ awọn ọrẹ Naijiria lo koro oju si iṣẹlẹ naa.

Aarẹ ni ijọba ko ni dẹkun gbigbogun ti awọn alakatakiti agbebọn yii afi igba ti awọn ba bori wọn patapata.

O ni ifarajin ijọba oun ṣi wa lati da abo bo ẹmi awọn ọmọ Naijiria bẹẹ ni awọn ko si ni ṣina tabi sojo tori awọn oniṣẹ laabi yii.

Tori naa, aarẹ ni oun ba awọn ẹbi awọn to faragba ninu iṣẹlẹ naa o si fi da wọn loju pe ijọba oun yoo tẹsiwaju lati maa funna mọ gbogbo igbesẹ aburu awn Boko Haram awọn yoo si mu u wa sopin.

Keteti awọn ọmọ Naijiria foju ganni eyi ni wọ́n han an mọ́ aarẹ Buhari lọwọ lori ayelujara.

Aarẹ Buhari 
Festus Keyamo (@alhassanixgeh) mu wa si iranti awọn eeyan, fidio ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu aarẹ Muhammadu Buari to ti wọn bi i nipa ohun ti ijọba rẹ yoo ṣe nipa abo ni Naijiria paapaa nigba naa lọhun ti Boko Haram ṣẹṣẹ n yọju, aarẹ fi yanwọ ọrọ naa sẹyin eti ni to si ni Boko HAram ko ja m nkankan.

Biliaminu Abdul Mujeeb Olaniyi ni tirẹ ni kii ṣe nipa bibani kẹdun ati ka maa kọ ọrọ soju opo Twitter o, bi ko ṣe pe awọn fẹ ri akitiyan kun akitiyan ati esi gidi.

Bash Mohammed oumar (@amur_bash) fesi pe bo tilẹ jẹ pe alatilyin Buhari ni oun. O ran Bashir Ahmad si ọga rẹ pe lootọ Buhari ti ṣe ọpọlọpọ lati tun orilede ṣe "ṣugbọn ni ti abo, o ti ja wa kulẹ. O nilo lati ja fafa". O ni ki Bashir ran an leti pe gbogbo eyi to ṣe ati eyi ti ko ṣe ni Ọlọrun yoo bere lọwọ rẹ.

Esi si ọrọ Aarẹ Buhari 
Ẹwẹ lori ọrọ kan naa, ~Izge~ (@shuaib_izge) ni oun kii e alagabagebe oun ko si ni j bẹẹ lailai. O ni aarẹ ana, Goodluck loun maa da ẹbi le lori fun aile koju iṣoro abo ni ẹkun Ila oorun Ariwa. Bẹẹ si ni o ni oun ko ni dakẹ bi Buhari gan naa ko ṣe ṣe nkankan.

Tosky Dada (@Dadasvc) fesi tirẹ bii afiwe ni pe didoju ija kọ Boko Haram jẹ didoju ija kọ ẹkun ariwa Naijiria ni.

Adam Mó (@adamm_mo) ni ọr oṣelu lasan ni gbogbo ẹ tori ilu Auno ko ju irin kilomita marun un pere lọ lati Bareke awọn ologun to to ọ̀wọ́ ogun mẹtalelọgbọn ni Maiduguri ti wọn si lee koju ikọlu yii laarin iṣẹju perete ṣugbọn ko sẹni to yọju titi ti awọn Boko Haram fi pa eeyan ọgbọn ti wọn si jo akẹkọọ fasiti Maiduguri meji di eeru.
Esi si ọrọ Aarẹ Buhari

Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI