APẸẸRẸ RERE NI ỌBASANJỌ JẸ KAAKIRI AGBAYE, ỌPỌ ORILẸ-EDE LO JA FUN - AARẸ BUHARI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, March 4, 2020

APẸẸRẸ RERE NI ỌBASANJỌ JẸ KAAKIRI AGBAYE, ỌPỌ ORILẸ-EDE LO JA FUN - AARẸ BUHARI

Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti gbe oriyin fun Aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, to si tun ṣapejuwe ẹ gẹgẹ bi aṣaaju rere to yẹ k'awọn eeyan maa wo awokọṣe rẹ.

Aarẹ Buhari lo sọrọ naa lonii lati fi ki Oloye Ọbasanjọ fun ti ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹtalelọgọrin (83) ti yoo waye lọla Tọside, iyẹn ọjọ karun-un oṣu kẹta.

Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina to jẹ agbẹnusọ Aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin fi sita lo ti sọ pe igbesi aye akikanju, ifọkansin, to si ṣiṣẹ takun-takun fun orilẹ-ede Naijiria, ilẹ Afrika ati aye ẹda lapapọ. 

Atẹjade naa ka bayii pe: "Aarẹ Buhari parapọ pẹlu idile, ọrẹ ati ojulumọ Aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹ lati ba a ṣayẹyẹ. Ifarajin Oloye Ọbasanjọ fun Naijiria ko ṣe e ko kere, to si nilo igboriyin fun.

Ọbasanjọ duro ṣinṣin, o si ja fun ominira ọpọ orilẹ-ede kaakiri agbaye."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI