O PARI O! DAPỌ ABIỌDUN FA IGI LE AYẸYẸ ỌDÚN ÌLÚ ILẸ̀ ÁFRÍKÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Thursday, March 5, 2020

O PARI O! DAPỌ ABIỌDUN FA IGI LE AYẸYẸ ỌDÚN ÌLÚ ILẸ̀ ÁFRÍKÀ


Ijọba Ìpínlẹ̀ Ogun lábẹ́ Gomina Dapọ Abiọdun tí jẹ kò di mímọ pé eto ayẹyẹ ọlọdọọdun nnì tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn káàkiri àgbáyé máa ń tori ẹ lọ s'ilu Abẹ́òkúta, ìyẹn ayẹyẹ ọdún ìlú ilẹ̀ Áfríkà (Drums Festival) fun t'ọdun 2020 kò ní í wáyé.

Ayẹyẹ Ọdún Ìlú Ilẹ Áfríkà lo bẹ̀rẹ̀ lábẹ́ ìṣàkóso Sẹnetọ Ibikunle Amosun. Ayẹyẹ t'ọdun yìí ni yóò jẹ àkọ́kọ́ tí Gomina Abiọdun yóò ṣe, ṣùgbọ́n yí wọn tí f'igi gùn ún wí pé kò ní í wáyé lọ́dún yìí.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ìpínlẹ̀ Ogun, pàápàá àwọn akopa lọdọọdun ni wọn ti ń f'oju sọ́nà fún ayẹyẹ náà, tí wọn sì ti ń retí ọjọ́ tí ìjọba yóò kéde ọjọ́ tí yóò wáyé.

Ọjọ́ Mọnde, ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù tó kọjá lo yẹ kí ìpàdé àwọn oniroyin wáyé láti kéde eto naa, káwọn èèyàn lè máa múra silẹ fún eto ayẹyẹ náà, ṣùgbọ́n tí a gbọ pé iwọde ifẹhonuhan táwọn èèyàn ṣe lòdì s'awọn ọlọ́pàá lórí bí wọn ṣe pá agbabọọlu kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Tiyamiyu lo padà jẹ́ kí wọn sún un síwájú.

Ṣùgbọ́n ni báyìí, ọrọ kò rí bẹ́ẹ̀ mọ rárá, nígbà t'ijọba sọ pé ayẹyẹ náà yóò di ohun ìgbàgbé fún ọdún yìí, àti pé àwọn kò ti í fẹ́ sọ̀rọ̀ lórí rẹ rárá.

Kò sí nǹkan méjì tí a gbọ pé ó jẹ́ ki ìjọba gbé eto naa ti sẹgbẹ kan, bí kò ṣe ti aarun tó ń tàn káàkiri àgbáyé báyìí, ti wọn si lo ó tún ti wọ Nàìjíríà, ìyẹn Coronavirus.

Ohun tó dájú ni pé ọpọ àwọn orilẹ-ede tó ń kopa ninu eto naa lo jẹ́ pé àarun náà tí de, tó fi mọ Ìpínlẹ̀ Ogun tó ń ṣ'agbatẹru ẹ. 

N'igbà to ń fìdí rẹ mulẹ, amugbalẹgbẹ Gomina Abiọdun lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Pasitọ Remmy Hazzan sọ pé k'àwọn èèyàn gbé ìrètí wọn tí sẹgbẹ kan náà nítorí àarun Coronavirus tó wà níta.

Remmy Hazzan làwọn tí mú ọjọ́, igbesẹ sì ti bẹ̀rẹ̀ lórí ẹ, ṣùgbọ́n ohun tó ń ṣẹlẹ̀ káàkiri àgbáyé lásìkò yìí kò ní í fáwọn láǹfààní láti kéde rẹ síta.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI