AYÉ O! BIṢỌỌBU OYEDEPO JÙ BỌMBU Ọ̀RỌ̀ ṢÍ AARẸ BUHARI, O N'IJỌBA APANIJAYE LO Ń ṢE E - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, March 9, 2020

AYÉ O! BIṢỌỌBU OYEDEPO JÙ BỌMBU Ọ̀RỌ̀ ṢÍ AARẸ BUHARI, O N'IJỌBA APANIJAYE LO Ń ṢE E


Aláṣẹ àti oludasilẹ ṣọọṣi Living Faith, ìyẹn Winners Chapel káàkiri àgbáyé, Biṣọọbu David Oyedepo tí ju bọmbu ọ̀rọ̀ ńlá lu iṣejọba Ààrẹ Muhammadu Buhari wí pé ìjọba aninilára lo ń ṣe lè àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí, tó sì ni asiko ijẹgaba rẹ tí fẹ́ ẹ pé.

Biṣọọbu Oyedepo lo sọ̀rọ̀ yìí lọ́jọ́ Àìkú, ìyẹn Sannde àná níbi ìsìn tó wáyé ní olu-iya-ijọ náà tó wà ní Ọta, Ìpínlẹ̀ Ogun. Nibẹ lọ sí ti fibinu sọrọ jáde láti bù ẹnu atẹ lu ijọba Buhari wí pé Baba isalẹ f'awọn ọ̀daràn ni.

O ṣàpèjúwe ìjọba náà gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò dára rárá, kò dá, tó tún sọ pé ìjọba rẹ lo kò àgbákò wọlé ju f'awọn ọmọ Nàìjíríà nínú àwọn ìjọba tó ti dárí orilẹ-èdè yìí.

Baba náà sọ pé ìjọba Buhari tún fẹ́ ẹ pá àwọn èèyàn lẹnu mọ láti má ṣe bù ẹnu atẹ lu ìjọba rẹ, ìdí rẹ tó fi ní kí wọn sọ ọ di òfin láti máa pá gbogbo àwọn tó bá ń sọ̀rọ̀ kugbakugbe sì ìjọba tàbí àwọn olóṣèlú, àtàwọn ọ̀rọ̀ tó ṣeé ṣe kó dá wàhálà silẹ láwùjọ, ìyẹn Hate Speech.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Àwọn òfin tí kò dára n'ijọba orílẹ̀-èdè yìí ń ṣe, Hate Speech. Wọn ní ti o ba fi ìkórìíra sọ̀rọ̀, ó ti paayan nìyẹn. Nínú ẹni tó sọ pé òun yóò paayan àti ẹni ẹni tó paayan, tó lọ ṣe? Inú ọgbà ẹranko tí a ń gbé yìí kò ye mi rárá.

"Mo ní kí ó má jẹ́ kí n woju ẹ, ó sọ pé ọ̀rọ̀ àbùkù ni, ṣùgbọ́n ẹnikan paayan, ó sì ń yan fanda káàkiri àdúgbò. Ọ̀rọ̀ rirun téèyàn kò gbọ́dọ̀ ronú nipa rẹ, depodepo wí pé yóò sọ ọ síta ni.

"Mo ní èèyàn burúkú ni ẹ, ó sọ pé mo ti daran. Ṣé kí n sọ pé èèyàn dáadáa ní ẹ nígbà tí ìwà rẹ kò dára?

"Lójú tèmi, èèyàn burúkú ni ẹ, ó ó sì yẹ lẹni tó lè ṣe adari. Mo yẹ lẹni tó lè sọ bẹẹ. Ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tòótọ́ ni mí, tí mo sì lọgbọn lórí. Nnkan burúkú tó ti ṣẹlẹ̀ sí Nàìjíríà ni ìjọba yìí, ko da ṣe ló dabi ègún. 

"Mo ti wá níbi tí pẹ, èmi ni mo kọ́kọ́ ṣáájú aawẹ àti àdúrà ni Nàìjíríà lọ́dún 1979. Mí ó kìí ṣe ọmọdé nínú ọ̀rọ̀ Nàìjíríà. Ìjọba tí kò dára rárá nínú àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè yìí re e, ìjọba tí kò mọ ibi tó ń lọ. Àsìkò perete ni wọn ní. Mo lè sọ fún un yín gẹ́gẹ́ bí í wòlíì pé asiko wọn tí ń ka ọjọ́ báyìí."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI