ẸẸMEJI Ọ̀TỌ̀Ọ̀TỌ̀ LÀWỌN ṢỌ́JÀ TÍ GBA MI LỌ́WỌ́ IKÚ ÒJIJÌ - MAKINDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 9, 2020

ẸẸMEJI Ọ̀TỌ̀Ọ̀TỌ̀ LÀWỌN ṢỌ́JÀ TÍ GBA MI LỌ́WỌ́ IKÚ ÒJIJÌ - MAKINDE


Gomina Ṣeyi Makinde t'ipinlẹ Ọ̀yọ́ tí sọ pé òun ké lè gbàgbé eemeji ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ t'awọn ṣọ́jà gba òun silẹ lọ́wọ́ ikú tó yẹ kó tí rán òun lọ s'ọrun aremabọ, àti pé ipa tí wọn kò lo jẹ́ koun ṣí wá láyé títí di àsìkò yìí.

Níbi eto t'awọn ologun tí 2 Division lábẹ́ Ọgagun Anthony Omozoje tó wà ní Tiger's Den, Adekunle Fajuyi Cantonment, Odogbo, Ibadan ṣe láti fi bù ọlá àti iyì fún un. 

Ó ní lára àwọn ọjọ́ tòun kò lè gbàgbé títí láì ni, tó sì ni lára rẹ ni ọdún 2007 tòun gbé àpótí ibo fún ipò aṣofin àgbà, ìyẹn Sẹnetọ. Ó lọ́jọ́ idibo gan án làwọn ọlọ́pàá yí ilé òun ka, ṣùgbọ́n àwọn ṣọja lo ni wọn gbé òun kúrò nílé lọ sí ọgbà wọn. 

Bẹẹ lo sọ pé ẹẹkeji ni igba tòun gbé àpótí ibo gomina lọ́dún 2015, tó sì ni ṣe làwọn èèyàn dá wàhálà silẹ níwájú ìta ilé alátakò òun, tó sì làwọn yìí náà lo kò òun yọ lọ́wọ́ wọn lọ́jọ́ náà.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI