ÌJÀ DÓPIN! OGD, AMOSUN, ỌṢỌBA ÀTI DAPỌ ABIỌDUN PARI ÌJÀ L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, March 7, 2020

ÌJÀ DÓPIN! OGD, AMOSUN, ỌṢỌBA ÀTI DAPỌ ABIỌDUN PARI ÌJÀ L'EKOO


Pupọ àwọn tó mọ òṣèlú tó wà láàárín àwọn gómìnà tẹ́lẹ̀rí nipinlẹ Ogun, ìyẹn Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba, Ọtunba Gbenga Daniel, Sẹnetọ Ibikunle Amosun àti Ọmọba Dapọ Abiọdun tòun jẹ gomina lọ́wọ́ lọ́wọ́ ni wọn mọ pe àárín wọn kò gún régé rárá.


Ko si nnkan méjì tó dá wàhálà silẹ láàárín gbogbo wọn bí kò ṣe ipò gomina tí wọn ń jà sì í. 

Ṣùgbọ́n ṣe ni ọrọ bẹyin yọ lónìí, Abamẹta Satide nígbà tí àwọn akíkanjú olóṣèlú yìí pàdé n'ilu Eko, tí wọn sì di ọrẹ padà.

Ọkàn lára àwọn ọmọ Ọtunba Gbenga Daniel lo ń ṣe ìgbéyàwó n'ilu Eko, nibẹ sì ni gbogbo wọn ti pàdé. 

Èyí ló ṣì ń jà nilẹ káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, pàápàá nípinlẹ Ogun tí wọn tí wá.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI