IWA AWỌN OBINRIN LO JẸ KI N FẸ IYAWO MẸJIDINLỌGỌTA (58) - ỌBA EṢU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, March 17, 2020

IWA AWỌN OBINRIN LO JẸ KI N FẸ IYAWO MẸJIDINLỌGỌTA (58) - ỌBA EṢU

Ọkan lara awọn babalawo loril-ede Naijiria, Simon Odo tọpọ awọn eeyan mọ si Onu Owa ti sọ pe b'oun ṣe fẹ iyawo mejidinlọgọta ki i ṣoju lasa, o ni iwa awọn obinrin lo jẹ k'oun gbe igbesẹ naa.

Onu Owa t'awọn kan tun n pe ni Ọba Eṣu sọ pe oun ki i bẹ obinrin lati duro sile oun, ati pe obinrin to ba tasẹ agẹrẹ l'ọdọ oun ko le lo iṣẹju mẹẹdogun t'oun yoo ti le e jade.

Ọba Eṣu ṣalaye wi pe ọpọ awọn ọkunrin ti wọn n ku lo jẹ pe iku wọn ki i ṣoju lasan, to si ni iyawo pupọ awọn ọkunrin to n ku lo jẹ afọwọfa iyawo wọn ni.

Gbajumọ Babalawo, ọmọ bibi ilu Aji n'ijọba ibilẹ Igbo-Eze North, n'ipinlẹ Ẹnugu sọ pe igba t'awọn iyawo t'oun ba fẹ ba ti sọrọ buruku s'oun l'oun maa n fẹ obinrin mi-in, tori pe oun ko lara lati gba iwọsi obinrin sara.

“Igba ti obinrin ba ti sọrọ buruku si mi ni mo maa n fẹ obinrin mi-in. Mi o le maa wo obinrin ko maa sọrọ si mi lai ṣe ohunkohun.

“Bi ọkunrin ogun ba ku ni Naijiria lonii, marun-un ninu wọn lo jẹ pe amuwa Ọlọrun ni, ṣugbọn awọn mẹẹdogun to ku lo jẹ iwa iyawo wọn lo fa a. Idi re e to fi jẹ pe igba ti obinrin ba ti sọrọ si mi ni mo maa n fẹ obinrin miiran.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI