Gbajugbaja oṣere tiata nnì, Fausat Balogun tọpọ
àwọn èèyàn mọ sì Madam Ṣajẹ ti sọ pe lara awọn oṣere tiata t'oun nifẹ si ju laye oun ni Ọdunlade Adekọla t'ọpọ awọn eeyan tun mọ si Mọnde Ọmọ Adugbo tabi Sunday Dagboru.
Madam Ṣajẹ lo tu aṣiri naa laipẹ yii, to si ni ko si nnkan meji to jẹ k óun fẹran Ọdunlade, bi ko ṣe ọrọ awọn mejeeji ye ara wọn yekeyeke daradara.
O ni latigba t'oun ti bẹrẹ si i ba Ọdunlade ṣiṣẹ pọ l'oun ti mọ awọn iwa ẹ, to si ni ọmọ oun to maa n gbọran s'oun lẹnu ni gbogbo igba ni.
No comments:
Post a Comment