O MA ṢE O! AGBABỌỌLU NAIJIRIA KU SINU IJAMBA MỌTO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 23, 2020

O MA ṢE O! AGBABỌỌLU NAIJIRIA KU SINU IJAMBA MỌTO

Iku agbabọọlu ikọ Rangers International ti ilu Enugu Ifeanyi George ṣe ni laanu gan na, bayii ni minisita fun ere idaraya ati ọrọ ọdọ, Sunday Dare ṣe n kẹdun

Ifeanyi di oloogbe lẹni ọdun mẹrindinlọgbọn pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ meji, Emmanuel Ogbu ati Eteka Gabrielinu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lanaa ọjọ Aiku.

Iroyin ti a gbọ ni pe ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn wa ninu rẹ lo lọ fori sọ ọkọ nla akẹru kan nibi ti o duro si.

Lopopona Agbor ni ipinlẹ Edo ni ijamba ọkọ ọhun ti ṣẹlẹ nigba ti George ati awọn akẹgbẹ rẹ n rinrin ajo ni opopona ilu Onitsha si Eko.

Alukoro ẹgbẹ agbabọọlu Rangers ṣalaye pe awọn agbabọọlu naa rinrin ajo lọ si ilu Eko lẹyin ti idije liigi Naijiria(NPFL) ti di siso rọ ki ijamba naa to ṣẹlẹ.

Ajọ ẹṣọ oju popo FRSC sọ pe awọn mẹtẹẹta lo ja laisi lojuna ti ijamba ọkọ naa ṣẹlẹ tan.

Minisita ni o ṣeni laanu pe pe awọn mejeeji ṣagbako iku ojiji lai le jẹ ohun ti wọn fẹ jẹ laye.

Minisita gbadura si Eleduwa pe ko tu awọn ẹbi awọn agbabọọlu mejeeji ninu, o ni oun naa kẹdun awọn agbabọọlu mejeeji.

Ẹwẹ, ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria, NFF sọ loju opo Twitter rẹ pe ibanujẹ nla ni iku awọn agbabọọlu mejeeji jẹ.

NFF kẹdun pẹlu ẹbi awọn oloogbe naa ati ẹgbẹ agbabọọlu Rangers Intl, ajọ naa gbadura pe ki Eleduwa tẹ wọn si afẹfẹ rere.

Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI