ABIỌLA JI ỌTÍ ẸLẸRINDODO, L'ADAJỌ BÁ NI KÒ LỌ R'OKO ÀYÍKÁ KỌỌTU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 21, 2020

ABIỌLA JI ỌTÍ ẸLẸRINDODO, L'ADAJỌ BÁ NI KÒ LỌ R'OKO ÀYÍKÁ KỌỌTU


Kani ki i ṣe ti arun koronafairọọsi to wa nita lasiko yii, ọgbà ẹ̀wọ̀n ni gendekunrin ẹni ọdún mẹtadinlọgbọn kan, Abiọla Ọlaniyi ko ba wa bayii, ti yoo ma a jiya ẹṣẹ rẹ pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n ọlọdun gbọgbọrọ.


Ọjọ́ kẹwàá oṣù yii la gbọ́ pe Abiọla lọ ọ ji ọtí ẹlẹrindodo ni ṣọọbu obinrin kan ti wọn pe ni Iyabọ Ṣoyọmbọ lagbegbe Ibara, Abẹ́òkúta.


Ibi ti Abiọla ti n salọ lọ́wọ́ palaba rẹ ti segi, to si mu ki wọn foju rẹ ba ile ẹjọ́ lọ́jọ́ Tọside ọ̀sẹ̀ to kọjá yii.

Abiọla nigba to n kawọ pọyin r'ojọ lo ti sọ pe òùngbẹ to n gbẹ oun lo mu k'oun lọ ọ ji àwọn ọtí ẹlẹrindodo naa ti owo rẹ ko din ni ẹgbẹ̀rún marundin-nirinwo (4,600) naira.


Agbẹjọro àwọn ọlọpaa, Tijani Isah sọ pe ẹṣẹ nla gba a ni Abiọla ṣẹ, to si yẹ ko gba ìdájọ́ rẹ bo ti tọ, ṣùgbọ́n ti agbẹjọro Abiọla, Olugbenga Apaniṣile ba a bẹbẹ.

Nigba to n gbe ìdájọ́ kalẹ, Onidajọ Ibilọla Abudu pàṣẹ pe ki Abiọla da owo ọtí to ji ko naa pada f'ẹni to ni i, ati pe yoo ṣíṣẹ sin ìjọba nipa riro gbogbo oko ayika kọọtu patapata ko to lọ sile lọ́jọ́ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI