O MA ṢE O! MISTA LATIN L'OUN KÒ L'ỌRỌ LÁTI SỌ L'ORI AISAN ÒGÚN-MAJẸẸKI, AGBA ÒṢERÉ TÍÁTÀ TÓ Ń ṢÀÌSÀN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 21, 2020

O MA ṢE O! MISTA LATIN L'OUN KÒ L'ỌRỌ LÁTI SỌ L'ORI AISAN ÒGÚN-MAJẸẸKI, AGBA ÒṢERÉ TÍÁTÀ TÓ Ń ṢÀÌSÀN


Ni ọjọ Aiku ni gbajumọ oṣere tiata kan lorilẹede Naijiria, Folukẹ daramọla gbee sita pe ojojo n ṣogun ara ogun o le fun eekan oṣere, Ogun Majek ti o si nilo amojuto to peye.

BBC News Yoruba kan si agba oṣere naa to si fi ye wa pe igbagbọ oun ni pe ẹgbẹ awọn oṣere n gbe igbesẹ lori ọrọ oun.

Eyi lo mu ki BBC News Yoruba gbe ọrọ naa tọ ẹni ti awọn oṣere tiata Yoruba yan gẹgẹ bi aarẹ wọn, iyẹn Ọgbẹni Bọlaji Amuṣan ti ọpọ mọ si Mr. Latin.

Ọgbẹni Amuṣan ni oun ko lọrọ lati sọ lori rẹ ati pe ki BBC News Yoruba o lọ bi Alàgbà Majek leere ohunkohun ti a ba fẹ.

Mr. Latin to n beere ohun gan to kan ileeṣẹ BBC lórí ọ̀rọ̀ ọhun ni ko sohun to buru nibẹ bi ileeṣẹ BBC naa ba da si ọrọ ọhun.

Gbogbo alaye akọroyin ileeṣẹ BBC lati jẹ ki o di mimọ fun ẹni ti awọn oṣere onitiata yan gẹgẹ bi aarẹ TAMPAN naa mọ pe ara ojuṣe ti ileeṣẹ iroyin lee ṣe fun pipe akiyesi iranwọ fun itọju agba oṣere naa lo bọ sẹyin eti rẹ to si ni oun ko lọrọ lati sọ nipa rẹ.

"Ẹ mọ nnkan to ṣẹlẹ, lori eleyii mi o ni ọrọ kankan lati sọ, ẹni ti ara rẹ ko ya, ẹ pe wọn, oun ti wọn ba ti sọ naa ni mo sọ"

'Ẹ o lee fi tipatipa mu mi sọrọ abi ṣe ẹ le fi tipatipa mu mi sọrọ ni'

Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI