ÀÌSÀN IBÀ LASSA TUN PAWỌN ÈÈYÀN TÓ TO ÌGBÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 11, 2020

ÀÌSÀN IBÀ LASSA TUN PAWỌN ÈÈYÀN TÓ TO ÌGBÀ


Ileeṣẹ eleto ìlera tó ń rí sì gbigbogun tí àrùn àti àìsàn lorilẹ-ede Nàìjíríà, Nigeria Centre for Disease Control, NCDC tí sọ pé àwọn mejidinlọgọsan {188} ni àìsàn ibà LASSA tí rán lọ sọrun laarin oṣù mẹ́rin.


Ọjọ́bọ, Tọside ijẹta àjọ NCDC fi ọ̀rọ̀ yìí síta wí pé yatọ tí àrùn aṣekupani Koronafairọs tó ń pawọn èèyàn lásìkò yìí, àìsàn ibà LASSA náà tún ń fi àwọn èèyàn logbologbo. 


NCDC sọ pé látìgbà tí ọdún 2020 tí bẹ̀rẹ̀ àwọn dín díẹ̀ lẹgbẹrun kan {963} ni wọn ti lugbadi àìsàn náà tó sì jẹ pe awọn mejidinlọgọsan {188} lo tí bá a lọ. 


Ó ní àwọn mẹta péré lo kú laarin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí tó sì jẹ pe ipinlẹ Edo, Ondo, Ebonyi, Bauchi àti Sokoto ni wọn tún ti àwọn tó lugbadi àìsàn náà. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI