VGN TUN GBARADA N'IPINLẸ OGUN LÁSÌKÒ KONILEGBELE, Ẹ WO IYE ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒKÙNKÙN T'ỌWỌ WỌN TẸ L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 10, 2020

VGN TUN GBARADA N'IPINLẸ OGUN LÁSÌKÒ KONILEGBELE, Ẹ WO IYE ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒKÙNKÙN T'ỌWỌ WỌN TẸ L'ABẸOKUTA


Béèyàn bá dé agbegbe Ibẹrẹkodo, Akọmọjẹ tó fi dé Arakanga nijọba ìbílẹ̀ Abẹ́òkúta North, ipinlẹ Ogun lákòókò yìí, yóò mọ pe àlàáfíà tó péye tí de ba àwọn ara agbegbe yìí. 

Kò sí nnkan méjì to fà á bí kò ṣe báwọn ọmọ ẹgbẹ́ eleto ààbò Fijilante, ìyẹn VGN pẹ̀lú ajọṣepọ àwọn ọlọpaa ṣe rọwọ tó àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn méje. 

Fáwọn tó bá mọ bí nnkan ṣe ń lọ làwọn agbegbe wọ̀nyí, láti bí ọdún mélòó kan sẹyin làwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn yìí tí wọn kọjú ìjà síra wọn, tí wọn sì ń pá ara wọn nipakupa, èyí tí wọn ní kó fi àwọn èèyàn lọ́kàn balẹ. 

Asiko ti gbogbo èèyàn wa nile yìí gẹ́gẹ́ bijọba àpapọ̀ ṣe pàṣẹ konilegbele là gbọ pé ọ̀rọ̀ náà tún bẹyin yọ, táwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà tún bẹ̀rẹ̀ wàhálà wọn.

Àná tí í ṣe Tọside là gbọ pé àwọn Fijilante tí wọn mọ gbogbo àgbègbè náà dáadáa dídé láti koju wọn, tí a sì gbọ pé ọwọ tẹ méje lára wọn. 

Àwọn méje tọwọ tẹ náà ni: Ọji; Samuel Ọlajide, ìyẹn Hollandia; Idris Adewale tí wọn ń pè ní 70; Ọyadeji Ṣọla ti wọn n pe ni Ṣọlabody; Tọheeb Tijani tí wọn ń pè ní Jẹgẹdẹ; Lateef Adedọpẹ tọpọ mọ sì Owo-ẹja àti Idowu Yussuf. 

Ọgbẹni Ṣorẹmẹkun John to jẹ́ adari ikọ ọtẹlẹmuyẹ fún VGN lo lewaju àwọn tó lọọ kò wọn.

Nigba tó ń fìdí ìròyìn náà mulẹ, ọga ẹgbẹ́ VGN, Kọmanda Nureni Ọlanrewaju Adedoyin sọ pé lẹsẹkẹsẹ tọwọ palaba àwọn ọ̀daràn náà tí segi làwọn tí fà wọn lé àwọn ọlọpaa lọ́wọ́.

Adedoyin ni pẹ̀lú ajọṣepọ àwọn ọlọpaa àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́ PCRC làwọn fi tọwọ tó wọn, tó sì làwọn tí sẹtan láti gbógun ti ìwà ibajẹ pátápátá, pàápàá lásìkò konilegbele yìí.

Ó ní agbègbè káwọn ara agbegbe Ifọ lọọ fọkàn ara wọn balẹ nítorí pé àwọn tí dìde láti dáàbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn èèyàn tó wà nibẹ. Bẹ́ẹ̀ lo ṣe ikilọ fáwọn ọ̀daràn wí pé kí wọn tètè fi ipinlẹ Ogun silẹ kò tó o pẹ ju nítorí pé àwọn tí sẹtan láti gbógun ti wọn. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI