AṢIRI GBAJUMỌ PASITỌ TO FIPA BA IYAALE ILE LAṢEPỌ NINU ILE AABO TU L’ABẸOKUTA, O TUN NI KO SẸNI TI EṢU KO LE YA LO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, April 9, 2020

AṢIRI GBAJUMỌ PASITỌ TO FIPA BA IYAALE ILE LAṢEPỌ NINU ILE AABO TU L’ABẸOKUTA, O TUN NI KO SẸNI TI EṢU KO LE YA LO

Ko sẹni to ri bi Samul obay to pe ara r ni Wolii san gangan e n sr nilu Abẹokuta laipẹ yii, ti ko ni i ṣiye meji pe iranṣẹ eu pombele ni, ugbn to j pe oruk Ọlọrun lo fi n lu awn eeyan ni jibiti.

Ohun to n ṣe ọpọ eeyan ni kayeefi lori ọrọ Samuel ni ẹbọ ti wọn lo maa n ni k’awọn to ba lo ṣiṣẹ lodo ẹ gbe laaarin oru, ti yoo si tun ko ibasun f’awọn obinrin, paapaa awọn iyaale ile, ko da, ti wọn lo o ti wa lnu iwa naa tip.

Iyaale ile kan ta a foruk bo lairi la gbọ pe Samuel fipa ko ibasun fun karakara ninu ile aabo ṣọọṣi ẹ to wa lagbegbe Oke-Akingbala, bantoko, nilu Abẹokuta.

AWIKONKO gbọ pe iṣẹ itusilẹ ni Samuel l’oun fẹ ẹ ṣe fun obinrin naa, ko to o di pe o sọ fun un wi pe afi k’oun ba a laep to ba fẹ ki iṣẹ itusilẹ naa tete dahun.

Gg bi a ṣe gbọ, wọn ni dun mfa syin re e ti iyaale ile naa a dede bẹrẹ si i mu ti karakara, ti wọn si lo n ṣe ọpọ eeyan ni kayeefi. Ọpọ awọn ile itọju la gbọ pe iyaale ile naa ti l lati jawọ kuro ninu ti mimu, ṣugbọn to j pe pabo lo n ja si, to si maa n da ija sil laarin oun ati ọkọ rẹ.

Oṣu kan syin la gbọ pe obinrin naa tun mu ti yii lamu-paara, ti wọn si lo o gbagbe ara rẹ sinu oko kan to wa ladugbo wọn. Ibẹ si ni wọn sọ pe kunrin kan ti wọn pe ni Baba Iyabọ ti ri i, to fi l’oun yoo mu l si ṣọọṣi kan to ti le ri igbala si ioro aye ẹ.

Ọjọ keji ni wọn ni Baba Iyabọ mu obinrin naa de ṣọọṣi Samuel, to si l’oun yoo ṣiṣẹ itusilẹ ọlọjọ meje fun un, ati pe aarin oru ni pupọ rẹ yoo j, nitori naa, o ni afi ko wa a ṣe igbele ọlọjọ meje ni ṣọọṣi oun.

Wn ni obinrin naa sọ pe oun ko le ṣe igbele, tori pe ọkọ oun ko ni i gba oun laaye. Idi re e ti wọn lo o fi ṣiṣẹ kan fun un, ṣugbọn ti iṣẹ naa pada baj nitori nnkan ou rẹ to ri. Eyi gan an lo mu ki Samuel sọ pe afi ko wa ṣe iṣẹ itusilẹ naa laarin aago mkanla si aago kan oru, nitori iw ati ẹbọ ti yoo gbe.

Ọjọ akk ti iṣẹ naa bẹrẹ ni wọn sọ pe Samuel sọ fun obinrin naa wi pe afi k’oun ba a laṣepọ ko to o le gbe b l s’ikorita, eyi ti yoo j k’iṣẹ naa le tete dahun, ti wọn si ni ṣe lobinrin naa yari pe ko le ee ṣe, ṣugbọn ti wọn lo o fgbn tan an w yara aabo ti wọn ti n gbadura, to si fipa ko ibasun fun un karakara.

Ọjọ ti iṣẹ naa yoo pari la gbọ pe Samuel tun ko ibasun fun obinrin yii, ti wọn si ni ṣe lobinrin naa muu mra plu igbagb wi pe oun yoo ri itusilẹ, ti ko si sọ fun ọkọ rẹ n’ile.

aaju asiko yii la gbọ pe awọn kan ladugbo ti wọn n ri obinrin naa ti pe k rẹ si akiyesi wi pe awọn maa n ri iyawo rẹ laaarin oru, ti yoo y klkl l si ṣọọṣi, to si ee ṣe ko j pe ale rẹ lo l naa ba. Idi re e ti wọn ni k obinrin naa fi ṣe iwadii, to si pada j pe otit ni.

r yii la gbọ pe o da wahala sil laarin obinrin yii ati k rẹ, bo til j pe ọtọ lni ti ọkọ rẹ ro tl wi pe o n yan iyawo oun ni ale, ṣugbọn ti airi pada tu wi pe Samuel t’awọn eeyan n wo gg bi Oluṣọ ni.

aaju asiko yii la gbọ pe pasit naa maa n y l sile obinrin yii lati ba a laṣepọ lasiko ti k rẹ at’awọn m ko ba si nile laar ati al, ṣugbọn ti i nnkan naa ṣe, to si j pe ọjọ kan ni airi fẹ ẹ tu, to si ri anfaani lati na papa bora.

k obinrin naa n’igba to n sr sọ pe oun ko m pe inu ewu loun wa lati bi ou mta syin ti iyawo oun ti n yan ale, to si lnikan lo tu airi naa f’oun ko to o di pe oun pada ri okodoro ọrọ.

O ni nnkan ti ko j koun m ni pe yara ọtọọtọ lawọn j n sun si, ati pe oun ko ronu nnkan bẹẹ si i ri. O lj ti airi yii maa tu, nnkan bi aago mejila ku iṣẹju mẹẹdogun loun taji, toun si l wo iyawo oun ninu yara, ṣugbọn toun ko ba, eyi lo mu koun lo o jokoo de niwaju ita, toun si ri i lasiko to sapam sinu gd nigba ti airi ẹ fẹẹ tu sw pasit kan to n gbe iwaju ile wọn.

Baale ile naa sọ pe kaka ki iyawo oun maa bebe, ṣe lo fesun kan oun wi pe oun ko toju oun, ati pe oun n lo s’ọdọ awọn to mo itọju obinrin ṣe ni, to si ee ṣe koun keru jade ki ọdun yii to o pari.

Ọkunrin naa tun sọ pe ọrọ naa to su oun lo je koun loo fejo sun Baba Imole, tawọn si lo beere nnkan to sele lodo Oluṣọ Samuel, o ni Oluṣọ naa sọ pe Baba Iyabọ lo mu iyawo oun wa si ṣọọṣi, ati pe ṣọọṣi naa ni wọn ti n ko ibasun funra wọn.

“Inu ile ni mo wa ti lose to koja lo lohun ti Oluṣọ yii tun ti wa a ba iyawo mi ni nnkan bi aago mewa koja iseju die, ti wọn jọ n sọrọ. Ko pe lo wa ki mi, ti mo si sọrọ buruku si i. ibe la ti bere ija, to fi ki ada mole, to si bere si i sa iyawo mi wi pe o tu aṣiri fun mi, ti ko si ri bee.”

Obinrin naa ninu ọrọ rẹ sọ pe Baba Iyabọ lo ran oun lw de ọdọ Oluṣọ Samuel to si ṣiṣẹ itusilẹ f’oun, ati pe igbele ọjọ meje loun ṣe, ṣugbọn toun yari pe oun ko le ṣe igbele.

O niṣe ọna ti Samuel kọkọ ṣe foun bajẹ nitori pe asiko naa loun ri nnkan oṣu oun, ati pe afi koun maa wa loru nitori awọn akanse iṣẹ to ro mo oru. L’ọjọ akọkọ, ṣe ni Oluṣọ sọ pe ki n to gbe ipese (ẹbọ) lo si ikorita mẹta, afi ka jọ ni aṣepọ, mo si sọ pe mi o le ṣe ẹ.

“Igba ti a de lati ibi ti a gbe ipese lo laago kan oru ni mo wo yara aabo, to si sare wle tle mi, o tilkun lyin, o si fipa ba mi laṣepọ. Lyin ọjọ karun-un ki iṣẹ naa to o pari, Oluṣọ tun ba mi laṣepọ ninu ile aabo, ti mo si sọ fun Baba Iyabọ, ṣugbọn to ni ki n ṣe suuru niwọn igba to j pe itusilẹ ni mo n wa, nitori naa ki n gba kamu.

lẹẹkta lo sọ pe ikorita ni maa ti w lo j ki n tun ranṣẹ pe Baba Iyabọ lati ran mi lw, nitori pe mi o le gba ko ba mi laṣepọ lẹẹkta. Alaal ni Oluṣọ maa n wa sile wa, ti mo si ti kilọ fun laimye igba.

“Eyi to wa gbyin yii lo di wahala. Ibẹ lo ti ro pe mo ti sọrọ fun k mi, ti mi o si sọ nnkankan. O sọ pe Baba Iyabọ lo n gbe mi wa si ṣọọṣi lati ba mi laṣepọ wi pe ki i ṣe oun, ti ọrọ naa si di wahala nla gidi. Ko pe lawọn eeyan pe mi wi pe mi o gbd de ṣọọṣi naa m tori pe Oluṣọ ti leri wi pe oun yoo pa mi danu.

“Ounj ni mo fẹ lo ra ti mo fi gba gb ṣọọṣi naa kja, bi Oluṣọ ṣe ri mi lo sare wa ba mi, to si fun mi n’igbati mj, ṣe lo tun sare lọ ọ mu ada pana, to si br si i fi lu mi, ti gbogbo ara mi bajẹ, o tun gba gbrun kan ati igba (1200) naira lw mi. gba mi lw ẹ o.”

N’igba t’oun naa n tako ẹsun ti wọn fi kan an, Samuel sọ pe “ti ni wọn lo n mu, ti wọn fi muu wa s’ọdọ mi, mo si ba a ṣe ipese to gbe lọ ọ si ikorita. Afi ki Ọlọrun aanu mi lori ọrọ yii. Inu ile aabo la ti jọ laṣepọ, funra rẹ lo si gba fun mi, ki i ṣe pe mo fipa muu rara.

Ẹẹkan ṣoṣo pere ni mo ba a laṣepọ, funra rẹ lo wa a ba mi ninu yara lyin to gbe ipese tan wi pe ki n ba oun laṣepọ, ti mo si gba fun un. Mi o a lada, ptpt ada ni mo fi luu, mo si ko ẹṣẹ bo o n’igba to wa pariwo le mi lori. Igi ina ti mo y, mo kan fi hal m-n lasan ni, mi o fi luu.

“Ko si ninu bibeli wi pe ka ba iyawo oniyawo laṣepọ, ṣugbọn mo m pe Ọlọrun yoo dari ji mi. Mo fẹ k’awọn eeyan foju aanu wo mi. Iyawo mi si ti kilọ fun mi lọpọ igba, ṣugbọn ko sni ti eu ko le ya lo, eu lo ya mi lo.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI