GBAJUMỌ ỌBA FIBINU ṢEPE F’AWỌN ARAALU NITORI OUNJẸ T’AWỌN OLOṢELU N PIN LASIKO YII - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, April 9, 2020

GBAJUMỌ ỌBA FIBINU ṢEPE F’AWỌN ARAALU NITORI OUNJẸ T’AWỌN OLOṢELU N PIN LASIKO YII

Beeyan ba gbọ bi ọkan lara awọn ọba alaye to gbajumọ daadaa n’ipinlẹ Ogun, iyẹn Ọba Tajudeen Arẹmu Kọlawọle Ṣowẹmimọ to jẹ Olu-Owode níjọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode ṣe n sọrọ laarọ oni lori ọrọ t’awọn eeyan gbe kaakiri ori ikanni aye;ujara, wọn a mọ pe inu kabiyesi naa ko dun rara pẹlu bi nnkan ṣe n lọ lasiko yii.

Asiko ti aarun aṣekupani ti koronafairọs yii n fi gbogbo agbaye kanna-kanna ko rọrun fẹnikẹni rara bi a ko ba ni i purọ tan ara wa jẹ.

Ki i kuku ṣe pe nnkan ti ọba naa n sọ ko ri bẹẹ, otitọ ọrọ pọmbele lo sọ f’awọn araalu lati ṣe atunṣe, ki wọn si tun ero wọn pa nipa iru awọn eeyan ti wọn yoo maa dibo fun lasiko idibo, to si ni ki wọn ye e gba owo tabi ounjẹ ki wọn to o dibo.

Ninu ọrọ ti Ọba Ṣowẹmimọ sọ, eyi to fi ranṣẹ si AWIKONKO laarọ oni lo ti jẹ ko di mimọ pe epe t’awọn eeyan n ṣe f’awọn oloṣelu lori ounjẹ ti wọn n pin f’awọn araalu lasiko konilegbe yii ko nitumọ, ati pe ara wọn ni wọn n ṣepe naa fun, ki i ṣe awọn oloṣelu.

Kabiyesi ni alatẹnujẹ l'ọpọ awọn araalu to n ṣepe f'awọn oloṣelu, to si ni nnkan ti wọn maa jẹ ni wọn n wa, wọn ko wa ilọsiwaju Naijiria, to si ni ko bojumu.

“Ọrọ ti mo fẹ ẹ sọ ko pọ, maa jẹ ko ya, ki n le sọ awọn eyi to jẹ koko nibẹ ti mo fẹ ẹ mẹnuba. Igba ti ọrọ aarun aṣekupani ti Koronafairọs di awuyewuye, ijọba sọrọ jade, wọn si paṣẹ pe k’awọn eeyan duro sile fun ọjọ mẹrinla pere, iyẹn ọsẹ meji lati le dẹkun itankalẹ rẹ.

“Boya o dara tabi ko dara, ẹ jẹ ka yin wọn tori pe nnkan iwuri ni wọn ṣe tori pe wọn gbẹsẹ, o si yẹ ka yin wọn. Ṣugbọn a o sọ pe gbogbo nnkan ta a fẹ ni wọn ti ṣe tori pe wọn gbẹsẹ, a ko si sọ nnkan ti wọn fẹ ẹ ṣe ti tan.

“Nipa ti nnkan abojuto, iyẹn ounjẹ ati owo (welfare package), gbogbo yin lẹ gbe baagi sori ikanni ayelujara, ti ẹ n pariwo sita wi pe wọn ko fun un yin ni elubọ, gaari ni wọn fun un yin, ẹ wa n ṣepe oriṣiriṣi. Gbogbo awọn epe yii, ori yin lo n pada bọ, nitori pe awọn to n ṣe oṣelu Naijiria ko jabọ lati ọrun, ẹyin lẹ dibo fun wọn lọ sibẹ. Ẹyin jakujaku tẹ n pariwo yii naa lẹ dibo lọ sibẹ.

“Kongo irẹsi ti wọn n gbe fun un yin yẹn naa lẹ n gba, ti ẹ fi n dibo fun wọn. Iye ti oṣuwọn aye yin ka naa ni iye kongo irẹsi ati gaari ti wọn n gbe fun un yin. Iwọ ti o gba kongo irẹsi kan to o fi dibo fun wọn lati ṣe ijọba fun ọdun mẹrin si ọdun mẹjọ, wọn wa a fun ẹ ni kongo irẹsi naa fun ọjọmẹrinla pere, o wa bẹrẹ si i ṣepe, ori ẹ gangan ni epe naa n pada bọ, nitori pe epe ti o n ṣẹ ko nitumọ.

“Ṣe iru asiko yii lo yẹ ki ẹ ṣẹṣẹ mọ pe awọn ti ẹ fi sibẹ ko mọ nnkan ti wọn n ṣe e. Aimọkan ti ẹ n ṣe ti pọju ninu iwa yin. Ọrọ Naijiria n dun gbogbo wa, ko sẹni ti ko dun, tori pe ibi ni gbogbo ẹni wa wa. A ti ẹni ti wọn n fiya jẹ, a ti ẹni to n fiya j’eeyan, gbogbo wa la jọ n jiya naa bayii. Ina ti ko si, ki i ṣe ile temi nikan ni ko ti si ina, opopona ti ko dara, ki i ṣe adugbo mi nikan lo ri bẹẹ, ileewe ti ko sunwọn, ki i ṣe ọmọ mtemi nikan lo maa lọ sibẹ. Ọsibitu ti ko ṣiṣẹ naa wa nibẹ, gbogbo wa la jọ n jiya yii. Ati ẹni to ra jẹnẹretọ nla, ati ẹni to ra kekere, iya kan ṣoṣo la n jẹ.

“Nnkan ti ko ye yin ni pe ẹni ti ko ba ti le to ile rẹ, ko le to ilu rara. Igba ti o ba gba owo, irẹsi, aṣọ lọwọ oloṣelu lati dibo, ko yẹ ki o maa tun ṣaniyan, ki wa ni gbogbo ariwo ti ẹ n pa. Ti wọn ba ni ki ẹ dibo ni ọla, ẹ tun maa gba owo riba naa ni ki ẹ to o dibo, wọn a tun fun un yin ni gaari ati irẹsi, ṣebi ẹni ẹ fẹẹ jẹ tiyin nibẹ ni, tiwọn lawọn n jẹ bayii, ẹ tun wa n pariwo, ki lo wa fa epe.

“Ṣe ẹyin ti gba iwa epe ti ẹ n wu sori na ki ẹ to maa ṣepe fun wọn? Ti Naijiria ko ba tẹ ẹ yin lọrun, ẹ maa ṣatunṣe ni. Gbogbo epe yẹyẹ ti ẹ n ṣẹ yẹn ko nitumọ, nitori pe ori elepe l’epe n pada si. Iwa epe to o wu, to o fi gba owo riba lọwọ wọn, o yẹ ki o ronu. O ran ole niṣẹ, o jale naa tan, o tun wa n pariwo, iṣẹ ti o ran naa lo lọ jẹ. Ori awọn eeyan wa yi ko pe rara, otitọ ibẹ niyẹn’

“Ilu ko toro, oṣelu maa to o, nibo niyẹn ti fẹ ẹ ṣẹlẹ? Ijọba ologun kọ la wa, ijọba alagba tiwa-n-tiwa la wa yii, nnkan ti o ba gbin lo maa ka, itumọ tiwa-n-tiwa niyẹn. Bi o ba yan ole sibẹ, ole naa lo maa ja. Ẹ ko le maa ba ilu jẹ, ki ẹ wa maa gbadura ki Ọlọrun ba a yin to o, ko ṣee ṣe. Ọlọrun ko le gba awọn adura abosi tẹ n gba yẹn, epe yẹyẹ ti ẹ n ṣẹ yẹn ko le mu wọn.

“Ayafi ti ẹyin ba n ṣe daadaa ni epe yin le mu wọn, epe yin ko le mu oloṣelu to ba n ṣe buruku, tori pe ẹyin naa n ṣe aburu. Onikaluku gbọdọ wo iṣẹ ọwọ rẹ ni, a gbọdọ bẹrẹ lati ile ni, tori wọn sọ pe ile la ti n kẹṣọ rode, ka si yẹ ara wọ daadaa.

“Ọpọlọpọ yin lo jẹ pe ole, onirọ, onijibiti ni yin, bi wọn gba yin sibiṣẹ, ẹyin naa lẹmaa ba iṣẹ oniṣẹ jẹ, ẹ si tun ma maa ṣepe fun oloṣelu. Nibo ni oloṣelu ti fẹ ẹ ri owo maluu fun ẹ ti ko ba jale. Oloṣelu to ba n ya ile gbe, wa a sọ pe ko gbọn, nibo lo ti fẹ ẹ ri owo ra ile si Banana Island ti ko ba ji i. Ori yin ko pe rara.

“Koko ibẹ ni pe bi Naijiria ba maa dara, gomina ko le to o, Aarẹ orilẹ-ede ko le to o, minisita kankan ko le to o, kọmiṣaana, kansẹlọ ati alaga lọka ko le to o, gbogbo wa la jọ maa to o nitori pe awọn kọ lo ba Naijiria jẹ, gbogbo wa la jọ ba a jẹ.

“lati inu ile to fi de ṣọọṣi ati mọṣalaṣi, to fi de ileewe lo ti bajẹ, ojuṣe gbogbo wa ni lati jọ to o. Ẹ ko le maa ṣepe yẹyẹ kan ti ko ni i ṣiṣẹ nitori pe wọn fun un yin lounjẹ, ẹ si fẹẹ tori ẹ ku. To o ba ma a ku ni ko o tete ku, ko sigba to o ni ku naa. Gbogbo wa gbọdọ sowọpọ lati tun ilu yi to ni. Koko ọrọ ti mo fẹ ẹ sọ niyẹn, ko sẹni to n ṣe wa, awa la n ṣe ara wa, otitọ si ni, ki ẹ lọ ronu si i.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI